O dàbí wí pé eléyìí ni ẹ̀kẹrin àlàyé mi nipa Taju Mẹkálíìkì ọrẹ mi nǹkan bí ọdún merindinlogun sẹ́yìn.
Mo kò ẹ̀kọ́ gidi láti ara Taju mẹkálíìkì eléyìí tí mi ò lè gbàgbé rárá. Ènìyàn tó bá rò wí pé òun ti gòkè kò rọra ṣe pẹ̀lú àwọn ará ilẹ̀. Nítorí ìrètí wá wí pé ènìyàn tó wà nílẹ̀ lè dìde, àdúrà wa ni wí pé ki ènìyàn tó wà lókè máà jábọ́.
Mí kò tilẹ̀ mọ wí pé Taju tí de pada. Ọ̀kan ninu àwọn ti won jo n ṣiṣẹ́ to ri mi lo béèrè wí pé se mo mọ̀ wí pé Taju ti dé.
Taju kìí fi gbogbo ìgbà wá sí wọkisọọbu won ayafi to ba ṣeré wá kí wọn. Eleyii ni Taju ń ṣe tí mi ò fi ni àǹfààní láti pàdé rẹ.
Ṣùgbọ́n mo padà rí lọ́jọ́ kan. Ara mi yágágá bí ìyàwó tó foju kan ọkọ rẹ̀ lẹ́yìn ọdún gbọọrọ.
Taju tí yato si Taju Mẹkálíìkì tí mo mọ̀ tẹ́lẹ̀, ó ti lómi lara àwọ̀ rẹ̀ ti si tutù bí ọmọ tuntun jòjòló. Ṣéèni jàgànnàn bí ti àwọn ọmọ olorin lọ gbe sọ́rùn pelu irun orí rẹ tí ń kó mọ̀nàmọ̀nà bí ẹyẹ ọ̀kín.
"Taju báwo ni? Ìgbà wo lodé? Se àlàáfíà ni?"
Èmi ni mo dúró níwájú Taju tí mo ń kí yii, tí mo ń yọ mọ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́ méjì tó ti ríra tí pẹ́. Pẹ̀lú bí mo ṣe ń kí Taju tí mo ń yọ̀ mọ ọ. Ń ṣe ló ń wò mí bí orí ẹran nibi to jókòó sí. Ó ń wò mí tìkà-tẹ̀gbin. O foju pamírẹ́ bí ẹni wí pé mi ò sì lórí ìdúró. Kò sọ̀rọ̀, kò wí ohunkóhun, okan sa n wo mi bi "tale lèyìí."
Ìtìjú mú mi, torí àwa méjèèjì nìkan kò la wà níbẹ̀. Mi ò mọ bí mo ṣe fẹ pasẹ̀dà. Mo dára mi lébi pátápátá wí pé mo yọ̀ mọ́ Taju. Se bi ènìyàn ṣe rí ní yìí? Ọkàn mi bàjẹ́. Taju lọ Libya ó dé, ó bẹ̀rẹ̀ si ni ṣe bí ẹni tí to tán. O n se bi eni ti mókè pátápátá, ó kápá sókè sebi alágbára.
0 comments:
Post a Comment