Ilé ayé kò tó o pọn. Bakan naa ni ko si nkankan nílé aye tó tó pọn gẹ́gẹ̀. Nítorí òfo ni, ki wa ni pàtàki ìgbéraga.
Àìmọye awon eniyan nla olókìkí ni mo ti ní àǹfààní láti bá sọ̀rọ̀ eléyìí tí ìwà ìrẹ̀lẹ̀ wọn je kàyéfì sì mí. Abalajọ tí wọ́n kò fi jábọ́.
Leyin igba náà, èmi àti Taju ó ṣòro mo. Bó bá rí mi, a gapá sókè bí ẹni kò sọdápaadi sapá. A wù sókè bí pọfupofu olóròóró. Á wò mí kọ̀rọ̀ bi ẹni wí pe Ọlọ́run ko lo sẹ̀dá mi. Ma ya kọjá mi lọ.
Mo sakiye pé àwọn tí wọ́n jọ ń sisẹ́ tẹ́lẹ̀ ni ìwa rè sí mi ń ṣe ní kàyéfì ṣùgbọ́n wọn kò lè dá lẹ́kun nítorí ojú ire rẹ ni wọn wa.
Joójúmọ́ ni Taju ń wọsọ tuntun, oríṣiríṣi bàtà, ó sì dabi ẹni wí pé ẹ̀yìn Taju nìkan ni Ọlọ́run wá nígbà náà.
Taju padà siluu Libya nígbà tó ṣe díè. Nítorí mi o ri mo, mi ò sì béèrè rẹ ṣùgbọ́n mo rẹni sọ fún mi.
Nígbà tó yá, ni akoko ti Gaddafi sì wá lórí òye gẹ́gẹ́ bi aare. Àìmọye ọmọ Nàìjíríà ní wọn lé padà wá sile latari ẹ̀sùn ìwà ibaje ti wọn wù niluu náà.
Gege bi iroyin to jade lọ́dún náà, ole, alonilowogba àti àwọn ìwà èérí ní àwọn ọmọ Nàìjíríà lọ ń ṣe nílùú náà. Eleyii lo fà tí wọ́n fi bere si lè wọn dànù.
Akoko naa ni Taju sapada wá. Àìmọye ọmọ Nàìjíríà náà ni wọn sa padà wálé. Taju sì ń ṣáko nígbà tó dé.
Ṣùgbọ́n ó padà na gbogbo owo tó kódé tan nibi to ti n se sekarimi kaakiri igboro. Ìtìjú kò sì jẹ́ kó lè padà sidi ise mẹkálíìkì tí ń ṣe.
Fun igba pípẹ́ sẹ́yìn ni mo ti dáríjin Taju, ṣùgbọ́n mi o lé gbagbe ìṣẹ̀lẹ̀ naa lailai.
O ti pe ti mo ti rí Taju kẹ́yìn, bakan naa ni mi lé so ibi tàbí ipò tó wà báyìí. Mo gbàdúrà kí àánú àti ojú rere Olúwa kò wá pelu rẹ.
0 comments:
Post a Comment