Àwọn oniroyin Amuludun tí ṣàkíyèsí wí pé, oríṣi ìtàn sinima tó tà julo lọwọ taa wa yìí ni ìtàn sinima tó ni ṣe pelu awada kẹrikẹri.
Àìmọye fíìmù alágbára ni Femi Adebayo tí gbé jáde bí ALAKORUN. Ṣùgbọ́n kò fẹ́ ẹ sì òkìkí fíìmù rẹ kankan tó lé JELILI bá.
Bákan náà ni ti a ba wo bí JENIFA se gbé Funke Akindele sókè ju àwọn ìṣe rẹ ìṣáájú lọ. Àpẹẹrẹ eléyìí náà lọ mú Toyin Abraham lọ sise lori ALAKADA.
Ní báyìí, Femi Adebayo tí padà sí oko ere láti sise lori Ipadabo Jelili Oniso pelu awon agba osere onira meje-méje lápá ọtun àti lápásì.
Ọdún 1974 ni wọn bí Femi Adebayo, ojúlówó ọmọ Ilorin Afonja sì ni. Ifafiti ijoba apapo tó wà n'ilu Ilorin lo ti kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nípa imo òfin. Leyin ẹyi lọ tún gboyè eleekeji nípa ìṣe tíátà.
Ayafi ti ènìyàn bá fẹ́ tigba kan bọkan nínú, a kò lè ṣàlàyé fíìmù ilé adúláwò pátá lai mẹ́nu bá ìdílé Adebayo láti Ilorin Afonja. Nítorí ojo aboki tí pé ní Sabo.
Lára àwọn fíìmù tí Femi Adebayo tí kopa ninu rẹ ni
October 1(2014)
Ayitale (2013)
Ladies Gang 2 (2011)
Atónà (2009)
Omo pupa (2008)
Owo blow (1995)
Tania (2015)"
Iya Alalake (2015)
Anini (2015)
Omo Ekun (2015)
Alagbaa (2015)
Onise Iku (2015)
Omo University (2015)
Ounje Ale (2015)
0 comments:
Post a Comment