Smiley face

Ìtàn Olajumoke arẹwà obìnrin (pt5)

OLAJUMOKE APA KARUN:

Won n jo lọ níwájú àwọn ọrẹ ọkọ njo bọ lẹ́yìn. Lẹ́yìn wakati die ohun abami kan sele......

hhmmm Jumoke boju wo eyin kori awon ọrẹ ọkọ rẹ mọ ayafi enikan ninu awon iwin yi ti oruko re nje Abami, (Abami je iranse Oriola. A má ba Oriola mojuto ile ati dukia nígbà tí ko ba si nile).

Eru ba Jumoke nígbà tí o ri nkan woyin, o bojuwo Oriola lẹgbẹ rẹ lati bèrè pe kilonsele si awon ọrẹ rẹ tí wọn fi pòórá.

Nigba ti  oju awon mejeeji pade eru tun baa nitori oju Oriola ti yipada di iwin. Igbayi loto mọ pe oun ti si oko wo.

Ó wa ranti gbogbo awon ọkùnrin ti ohun tí fi rera.

Loba bẹ̀rẹ̀ sini sunkun, o ni ti mo ba ti mo n o bati fe awon eeyan gidi bii temi, modara modara lowa ba temi je bayii haaa ori iya mi ooooo....

Oke ètè re ń gbọn ṣùgbọ́n ko reni rẹẹ lekun. Nígbà tí won rin ibuso die lotun sakiesi pe apa otun Oriola jabo lara re o si pòórá.

Eru tun ba gidigidi o tún kigbe e gba mi oooo iyaaa mi ooo sugbon kori enikan ayafi iwin mejeeji yii...

Ẹ maa bawa ká lọ ... E KU OJU LONA ITAN ALARINRIN  MIRAN.

Orísun: Emmanuel Oluwafemi Felix

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment