OLAJUMOKE APA KEFA :
Bi won tun serin ibuso die si o kiyesi wí pé apa osi Oriola tun jabo sile o si tun poora, jinijini mu Olajumoke lo ba tun figbe ta... yeeee... e gbami oooo...
Oriola wo oju Olajumoke lo ba pose saarasa o ni... eyin omo adarihunrun kilode ti e koni itelorun naa OLODUMARE lo mo eto fun ohun gbogbo t'oda atipe ninu gbogbo ise OLODUMARE eniyan nikan lọ yàtò.
Bi o se nsoro lo ni ẹsẹ otun re ba tun jabo l'osi tun poora, asiko yi gan-an ni Olajumoke wa bẹ̀rẹ̀ si tọ sara pelu ekun ni sísun.
Leyin ibuso die ni ese osi naa tun jabo lo ba tun poora, lo ba nwo Oriola to ń rákò rò nílé.
Nigba t'oya ni gbogbo ara Oriola ba poora, o wa ku ori nikan to ń yi nile gbirigbiri.
Oro na wa toju su Olajumoke nitori ko wa mo iru odo t'ohun yio da orunla sì.
Nitori iwaju kose lo beeni eyin ko see pada si, o wa ku oun nikan ati ewa re lowo iwin ati abami tiise iranse Oriola.
Ẹni a wi fun oba je o gbo eni a sọ̀rọ̀ fun oba je o gba.
Leyin eyin kilo tun sele, e pade mi ni apa keje nitori alo sese bere ni, e maa bawa kalo........
0 comments:
Post a Comment