Smiley face

Agbara To Gbe Mi Subu Lo Gbe Mi Dide

Igba ti mo wa ni kekere, o maa n ba mi lokan je wi pe bawo ni mo se ni ori ki n maa ra bata ti ese kan maa n fi gbogbo igba kere ju ekeji lo. Ni gbogbo igba ti mo ba ti ra bata saa ni bata ese otun maa n fun mi dain-dain ju ti ese osi lo.

Sugbon igba to ya, mo se akiyesi wi pe ki i se wi pe awon bata ti mo n ra ni ese otun re maa n kere ni gbogbo igba, ese otun mi lo fe tobi die ju ese osi mi lo. Eleyi si maa n fara han nigba ti mo ba n lo bata naa lo, bata ese otun mi maa n tete ran ju ti ese osi lo.

Iru nnkan bayii naa maa sele si awon obirin naa to je wi pe oyan kan le fe tobi die ju ekeji lo. Iru awon nnkkan bayii ki i se aleebu, abuda ni.  O wu Olorun lo fi agbara fun awon eya kan ninu ago-ara wa ju omiiran lo.

Opolopo nnkan agbara ti eniyan le fi owo otun se lo je wi pe owo osi ko le se ida kan re bee enikan naa lo ni owo mejeeji.
Agbara to Gbe Mi Subu Lo Gbe Mi Dide


Bi mi o tile ri onimo isegun oyinbo lati salaye iru awon nnkan bayii fun mi, sugbon mo gba ninu ero mi wi pe awon idi pataki kan wa ti Adaniwaye fi se awon nnkan wonyii bee fun awon ohun pataki kan ninu igbe aye eda ni ( Bi o tile je wi pe pupo awon idi pataki bee la o mo rara).

Bi o se n sele ninu ago ara enikookan ti agbara wa fun eya ara kan ju okan lo, yala eti otun a maa tete gboran ju osi lo lai se wi pe eti naa yonu bee gege naa lo n sele laaarin omoniyan tabi awon eda gbogbo.

Awon ojogbon ti sise nipa wi pe bakan naa ni opolo eda ri. Ilo opolo ati iha ti eniyan ko si iru igbe aye to fe gbe ni o so bi opolo re yoo se jafafa si. Eyi ni wi pe bi eniyan ba se lo opolo re ni yoo le so fun wa boya opolo eni bee yoo pe tabi yoo ku bi akurari.

Ninu ero mi mo tako iwadii naa. Iriri mi ati akiyesi mi si fi ye mi wi pe mi o se asise.  Gbogbo wa le ni iru opolo kan naa, sugbon agbara opolo wa ko dogba rara. Awon nnkan wonyii ki i si se aleebu rara oni idi pataki ati wi pe atoka si igbe aye to ye ki eda gbe ni.

Eko isiro je ohun to maa n fun mi wahala pupo gan-an. O si maa n gba mi ni opolopo akoko ati irori ki n to mesi to girimo jade- pupo ni awon esi bee lo tun ma n je odo. Ki i se wi pe boya ori mi ku, tabi aijafafa mi nipa eko isiro je abawon tabi aleebu.

Bi mo se feran orin kiko to, ohun mi o korin. Agbara ohun orin ko si ninu ohun mi bee si ni ko si ni ona ofun mi.

Opolopo awon agbejoro ti mo mo maa ni eti igboran nipa suuro ati iteti gbo ohun ti enikeni ba n ba won so ni akoko kan. Ironu won si maa jinle gidi. Eyi ko so wi pe won dara ju awon eniyan ti won ki i ni suuru ati iteti gbo oro lo, eyi kan se afihan ibi agbara enikan ti gbe ju ti enikan lo nipase ebun tabi abuda kookan to yato si ara awon.

Iru agbara ti a ni n se apejuwe iru igbe aye ti o ye ka gbe. Bi o tile je wi pe aimoye agbara lani ti a ko ti se awari tabi imulo re, ohun to daju ni wi pe opolopo agbara ni eda kookan mu wa lati ode orun.

Opolopo awon eniyan ti won ko feran ejo maa n je eniyan jeje, opolo eniyan jeje maa ronu lopolopo eleyii to maa n fi won han gege bi ologbon. Ti e ba si sakiye awon eniyan jeje e ri wi pe won ki i loyaya, bakan naa ni won kii lore tonkan. Bi onisuuru se wa je ologbon ko so wi pe omugo ni elejo wewe. Ohun elejo wewe le se ogbon onisuuru le ma ba fogun odun.

Ohun ti mo fe so gan-an ni wi pe anfaani wa ninu agbara aleebu bakan naa ni anfaani wa ninu aleebu gbara.  Boya aleebu tabi anfaani, agbara ni awon mejeeji je a si gbodo fi oju agbara wo won ninu igbe aye wa.

Olayemi Oniroyin, ohun ti mo fe so gan-an mi o ti so. Alaye ti mo fe se gan-an mi o ti gbe kale. Ifaara lasan leyi, eyin e kan ba mi dimu titi maa fi daride. A mo ki n to lo, e ri agbara ninu ipokipo ti e le wa. Aleebu yin ko ye ko je okunkun ti yoo bo yin loju, o ye ko je imole lati dari yin sibi ti agbara yin wa ni.

E ku ikale
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

1 comments:

  1. Olayemi oba, gbogbo igba ni mo maa n gba dun e bi igba eniyan n j e jollof rice ati eran dindin.

    ReplyDelete