Morufa Eko ti fi leta eleekafa re ranse, eyi si dun mo wa ninu pupo. Fun anfaani eyin ti e ko mo ibi ti a ba de ati eyin ti ko mo ibi ti a ti n bo, mo royin ki e ye awon leta ateyinwa Morufa wo [NIBI].
Sii Olootu Olayemi Oniroyin,
Ni ale Satide to ku emi ati oko anti mi nile. Sebi e o gbagbe wi pe anti mi ti lo si ilu Ibadan. A le ojo naa ni mo si pinnu lati fun oko anti mi ni majele je bi o tile je wi pe ore mi gba mi niyanju lati maa
fe oko anti mi ki n le ri owo gba lowo re.
fe oko anti mi ki n le ri owo gba lowo re.
Mo gbe ounje fun oko anti mi. O je tan raurau, ounje naa ko si ku nnkankan ninu abo. Mo pada sinu yara lale ojo naa mo si pada si ni sunkun. Ohun to n pamilekun gan-an ni oro ile aye mi ati awon ohun ti mo ti fi owo mi se.
Se bo se ye ki aye eniyan ko ri ni yii? Sebi ti eniyan ba wa ile aye, o ye ko gbadun aye re ni. Mi o tesiwaju ninu eko mi, mi o tun ri ise kan pato ko bi ti awon egbe mi ti a jo jade ile iwe sugbon ti won ko le tesiwaju mo.
Nibi mo ti n danikan ro oro aye mi, ero kan tun so si mi lokan pe ki n seku pa ara mi. Boya ti mo ba ku, okan mi yoo ni isinmi ayo.
Mo wo ago kekere kan to wa lori tabili mi, owo kekere ti duro lori mokanla nigba ti owo gungun ti ye kuro die lori mejila.
Ariwo gan-an ko si nita mo, yato si awon moto ti n koja lekookan.
Onikaluku ti wo inu ile re lo sun, yato si awon omo orita to je wi pe orita ni won ti n je, orita naa ni won sun si.
Mi o jade kuro ninu yara mi, sugbon o daju wi pe oko anti mi gan-an yoo ti wole lo sun. Gbogbo re palolo bi iboji oku. Bi abere ba jabo, gbonrananran re yoo dun leti.
O remi sinu, oju mi si n se belubelu bi atupa to ti fe ku. Mo paju de mi o si mo igba ti orun gbe mi lo.
Igba to ya, okunkun su bole. Gbogbo inu yara mi si dudu birimu.
Se awon NEPA ti tun mu ina lo ni? Igba wo naa ni won mu ina naa de ti won tun fi mu lo pada? To ba ti pe ti eniyan ti wa ninu okunkun, oju o bere si ni riran diedie, bi o tile je wi pe irinran naa ki i se eyi ti o mole kedere.
Mo boju wo apa keji egbe beedi ti mo sun si, okunrin dudu kan lo duro sibe. Ara re n dan boroboro bi eni o fi ororo para. Mi o tete ri oju eni naa daada, sugbon eniyan to ga to ki sara ni, igbaaya re si ri gelete bi eru okirika ti won di kale.
Sebi mo tilekun ki n to sun? Abi mi o ti rara ni ti mo sebi boya mo ti. O ni lati je wi pe mi o ti ilekun naa. Bawo ni eniyan se fe wole to ba je wi pe mo ti ilekun mi? Kayeefi leyii saa je fun mi.
Mo tun tiraka lati ya oju mi daada ki n le ri eni naa. Igba yii ni mo wa sakiyesi wi pe eni naa n po eje lenu.
O n fi owo osi gbe eje ti n jade lenu re, o fi owo otun mu obe gigun kan dani bi eyi ti awon hausa mai suya fi n ge eran. Eni naa n gbiyanju lati soro, sugbon eje ti n jade lenu re ko je ko le soro daada.
Jinijini bo mi, mo ti ra mo ori beedi ti mo wa. Iru ki leyii? Oko anti mi fe fi obe owo re gun mi abi ki lo fe fi se?
Ohun ti n so ta si mi leti ninu eyi to so gbeyin: "Ko o to ran mi lorun ojiji, iwo loo koko lo," ohun ti mo gbo ni yii.
Bo se so eyi tan, bee lo gbe obe owo re soke, o si fi gun mi mole laya mo ori beedi ti mo wa.
Aya mi ja, eru ba mi, mo si fo dide nile lojiji lati oju orun ti mo wa. Iru ala buruku wo leyii?
Kini itunmo eleyii, se ki n se wi pe apere wi pe iku mbo leyii? Eleda mi gba mi, mi o mo gbodo ku. Iku bi ti ba wo? Mo joko si eti beedi mi, bee ni mo n mi gule-gule bi eni oko jaale. Aagun bo mi ni gbogbo ara bi eni to sese jade ni baluwe ti o ti nura.
Okan mi o bale rara, bakan naa si ni ara n fu mi nitori mi o la iru ala bee ri laye mi. Mo ye igbaya mi wo, ko maa lo je looto ni won ti fi obe gun mi. Sugbon ko si ohunkohun nibe, okan mi tun bale die si.
Nibi ti mo wa ni mo gbo ti enikan kan ilekun yara mi? Mo gboju wo ago to wa lori tabili, aago kan oru ti koja iseju mewaa.
"Morufa....Morufa....Morufa" Eni naa n pe mi. Ohun oko anti mi ni mo n gbo.
Oko aunty mi naa ni mo ri loju orun to gunmi lobe pa. Se ki se wi pe ala ti mo la fe se bayii. Bo se n pe mi ni mo n gbo sugbon mi o dahun. Se fun rara mi naa ni ma tun fi owo ara mi silekun fun iku ti o
pami ni bayii? Sugbon ohun re ti mo gbo ko dabi eni ti n po eje lenu.
pami ni bayii? Sugbon ohun re ti mo gbo ko dabi eni ti n po eje lenu.
Ohun re ja geerege, mo si n gbo oro enu re ketekete. Mo dide lo lati si ile kun fun-un. Igba ti mo de enu ilekun, mo duro.
"Ki le fe ki n se fun yin?" Mi o ti si ilekun ti mo fi n bi leere oro. O ni ohun fe ri mi ni pe ki n silekun.
Ki lo fe ri mi fun? Se ki n se wi pe o tun fe bo mi mole ko tun fi tipatipa ba mi sun gege bo ti se tele?
Mi o soro soke, mo kan ro sinu lasan ni. Mo pa okan mi po, mo si ilekun fun-un.
Oko anti mi: Morufa mo wa lati wa ba o soro pataki ni.
Emi: iru oro pataki wo le fe so ti o le je kile mo?
Oko anti mi: Oro to ba gbale enikan kii faaro so. [O n rin lo taara lo joko sori beedi mi].
Bee ni mo n wo tika-tegbin. Se kii se wi pe omokunrin yii tun ti pada wa se ise ibi owo re. Mi o sun mo, enu ilekun naa ni mo si wa ti mo n wo. Iru wahala wo leyii, talo ni ki n silekun fun na?
Sebi mi o ba ti maa dibon bi eni to sun. Sebi eni sun laaji, enikan kii ji eni piroro. O n wo oju mi, emi naa n wo nibi ti mo duro si legbe ogiri to kangun si ilekun abajade. Igba to ya lo n tu apo sokoto re jade. O ko owo jade, owo naa po die. O ko owo naa sori tabili.
Oko anti mi: Mo wa be o fun asise ti mo se ni. Egberun lona ogun naira ni yii, mo fun o, mo si fe ko darijin mi patapata. Mo si ti bere si ni ronu lori ona ti mo le gba ran o lowo, ti iwo naa yoo fi di eni ti n lowo lowo ti o maa fi se bisineesi ti e na.
Oju mi to ti wa loke pada wale. Oju ti mo ti faro, tuka. Oro enu re n mu ara mi tutu pese bi omi inu amu. Se kii se wi pe ogun ni omokunrin yii lo wa ba mi, abi owo ti mo ri lo so mi dode ni?
Egberun lona ogun naira. Mi o reni fun mi legberun mewaa odindin ri laye mi. Gbogbo oro ti n so, mi o fun lesi. Mo kan saa duro sibe, a n wo ara wa. Igba to ya lo dide wa bami. O fowo le mi lejika, mo n wo oju re, oun naa si teju mo mi.
Oko anti mi: Morufa, mo nife re gidigidi. Je ka maa fe ra wa, ko sewo. Sebi emi lokunrin, mo mo ona ti n gbe gbogbo re gba.
O di mo mi, sugbon mi o tura ka si. O fa mi mora sugbon mi o wo oju re; mo gbe oju mi segbe kan. O fa mi lowo lo sibi ti beedi mi wa. Mo n tele sugbon mi o kobi ara si...
Eyin temi, mo mo wi pe yoo dun yin wi pe mo tun danu duro. O wu ni ka jeran pe lenu onfa oloofun ni ko je. O wu mi ki n tesiwaju, ilana ati ofin ti won fi lele fun mi nipa iye onka oro to le jade leekan naa ni ko gba mi laye lati maa salaye mi lo laidanu duro. Ni agbara Eledumare, ayo ati alaafia ni maa tun pada ba yin.
E ku asiko yii.
Emi ni Morufa Eko
0 comments:
Post a Comment