Lati inu iwe iroyin Alaroye to jade lose yii ni iroyin naa ti lu jade wi pe alaga egbe PDP ti ipinle Ekiti gbe iyawo re lo si ile ejo lati tu igbeyawo won ka.
Nibayii, ile ejo ti tu igbeyawo to wa laarin Oloye Kolawole Idowu Faleye ati iyawo re to bi omo meji fun ka.
Lara esun Ogbeni Faleye, eni odun mejilelogota (62), ni wi pe iyawo oun ni agidi, kii gboran ati wi pe wahala re ti poju.
Ogbeni Faleye to je okan lara igi leyin ogba fun Gomina Ayodele Foyose nigba eto idibo so wi pe oun o nife iyawo oun mo ati wi pe ki ile ejo fi igi fo igbeyawo naa danu.
Oludajo ti tu igbeyawo naa ka bayii. Gbogbo re si ti pari.
Fun ekunrere alaye, ati awon iroyin mi-in, e gbiyanju ki e ra iwe iroyin ALAROYE to jade lose yii.
0 comments:
Post a Comment