Smiley face

Morufa Eko 12: Awon Olopaa Lo Gbe Santana Oko Afesona Mi

Sii Olayemi Oniroyin,


Morufa Eko tun ti de o. E ku amojuba mi. Itan igbe aye mi ti mo ti n baa bo lenu bi ojo bi melo kan dabi eni wi pe o ti fe fenu gunle bayii. Gbogbo igba ni i ma maa dupe fun ife ati aduroti yin.
Paapa julo, Olayemi Oniroyin Agbaye. Gbogbo igi ti elegbede ba fowo ba, didun ni i dun.

E je ka pada gbe e nibi taa ti duro ninu leta ti mo ko keyin….

Owo awon olopaa te Santana lodo egbon re to salo ni Badagry. Awon olopaa bere ajosepo to wa laaarin emi ati e, ati wi pe ibo lo fi mi pamo si.

Igba ti owo iya awon olopaa dun Santana daada, o bere si ni jewo gbogbo ohun to wa laaarin emi ati e lai fi akoko sofo. 

Sebi iya ko to ya ni omode ni ko ni daa fun eni to na un. O so nipa oro ife awa mejeeji. Bakan naa lo tun so fun awon olopaa wi pe mo so fun oun wi pe mo loyun foun. 

Sugbon oun ko jale wi pe oun ko ni oun loyun naa. O ni oun binu lojo naa ati igba naa ni awa mejeeji ko si ti foju kanra mo. 

Awon olopaa beere idi ti Santana fi ko oyun ti mo ni fun-un.
O ni oun ko le gba iru oyun bee nitori oun mo wi pe oun nikan ko ni mo n fe. Awon olopa beere wi pe taa tun ni mo n fe leyin re. 

O ni oun o mo, sugbon o da oun loju wi pe oun nikan ko ni mo n fe. O ni idi ni yii ti oun fi ko lati gba iru oyun bee.

Lori awijare Santana fun awon olopaa: otito ni Santana so. 

Bi mo se n ni ajosepo pelu Oko anti mi bee naa ni emi ati Santana n pade gege bi ololufe meji. Igba ti mo se akiyesi wi pe mo loyun, odo Santana ni mo koko lo. Sugbon n se lo faake kori wi pe oun ko ni oun ni oyun naa.
Sebi won ti iwaju ko ba se e lo, eyin o see pada si lo je ki n pada si odo oko anti mi. Oko anti mi ti mo si pada si, kii se eni to wu mi lati loyun fun. Ju gbogbo re lo, mi o le so boya Santana lo loyun ni abi oko anti mi.

Ninu ero awon olopa, awon olopaa ni pelu iru iwa ti Santana wu, oseese ki n lo gbiyanju lati lo se oyun naa nibi kan eleyii to seese ko pamilara tabi ko je wi pe iro wa ninu oro Santana. 

Igba ti awon olopaa mu Santana, egbon re to salo ba naa tele e. 

Awon olopa bi egbon re boya Santana so ohunkohun to gbe wa si Badagry lojiji tabi boya egbon re ri enikeni mo o nigba to de sodo re.

O ni oun ko ri enikeni moo rara. O ni ohun ti Santana si so ni wi pe ise ni oun wa wa si Badagry, ati wi pe oun fe wa ise lo si ilu Cotonue. 

O ni oun kan fe wa lodo oun fun igba die ki oun fi ribi gba lo. Egbon re ni ko so ju ba un lo fun oun. 

Won beere lowo anti mi boya o mo pe mo loyun, anti mi ni oun o sakiyesi wi pe mo loyun. O ni ayafi bi oun se gbo bayii fun igba akoko. 

O ni kini kan ti oun sakiyesi ni wi pe mo maa kompileeni wi pe ara mi o ya nigba gbogbo. O ni oseese ki oro naa je ooto. 

Aburo baba mi ti pada sile nigba to ti ri oju ile lati lo fi ese-ile to oro naa ki asiri ibikibi ti mo ba wa le tu jade. Egbon mi ati iya mi ni won sare kiri igboro Eko lati wa mi ri.

Awon olopaa lo tu inu eru mi nile boya won le ri nnkan to le to won sona. Won ri opolopo owo ninu eru mi. Won si tun ri awon foto ti emi ati ore mi Tolani ya, won beere bi Tolani se je. Won fi ye won wi pe ore mi ni Tolani. 

Lowo kan ni awon olopa lo gbe Tolani.
Kini Tolani so fun awon Olopaa?
E tun pada pade mi lakotun.

Emi Ni Ti Yin Ni Tooto,
Morufa Eko






















Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment