Smiley face

Morufa Eko 13: Asiri Oko Anti Mi Tu Sowo Awon Olopaa

E ku deede iwoyii eyin ololufe wa. E mi Morufa naa ni mo tun un ki yin.




E ku ifomoniyanse. Se e o gbagbe ibi ti mo ba alaye mi de. Won ti gbe Santana oko afesona mi. Awon Olopaa si ti fi oro wa a lenu wo nipa wi pe ko jewo ibo lo gbe mi si. 




Laiforo gun rara, awon olopaa tun tanna iwadii won de odo Tolani ore mi. Ibi ti mo ba leta mi de nu-un

Won ko tile tii beere ohunkohun lowo Tolani to ti beere si ni se gbogbo alaye fun awon olopaa. O bere pelu bi oko anti mi se koko fi ipa ba mi lopo. 


O so fun anti mi wi pe ojo ti mo ni okada gba mi, kii se okada, ojo naa ni oko anti mi fi tipatipa ba mi lopo.
O ni oko anti mi maa n fun mi lowo gan-an, o ni gbogbo bo se n fun mi lowo ni mo maa n so fun oun pata. O ni lose to koja ni mo so fun oun wi pe oko anti mi n mu mi lo sibi kan lati lo ba mi seyun. O ni eleyii waye leyin igba ti mo so fun oun wi pe mo ti loyun. 

A ti wi pe oko anti mi ni mo so fun oun wi pe o ni oyun ikun mi.

Igba ti Tolani soro kale, n se ni awon eniyan yanu sile ti won o si le panude. Anti mi bu sekun nigba to gbo gbogbo oro naa. Oko anti tako Tolani wi pe iro ni gbogbo alaye to se. 

Sugbon o jo bi eni wi pe anti mi gbagbo wi pe oko oun le se iru nnkan bee tabi ko ti gbo nnkan to mu ifura dani tele eleyii ti ko kobi-ara si. N se lo n gbara yile to si n sunkun. Bo se n sunkun lo n ni oko oun ti ba aye ohun je o.




Leyin asiri oro to tu lati enu Tolani, okiki isele naa tu wa kan eleyii ti gbogbo eniyan ti ko mo tele tun wa n gbo sii. 




Awon olopaa mu oko anti mi lo lati te e ninu ko le jewo. Awon olopaa se iwadii nipa akoko ti mo fi iso anti mi sile pelu igba ti oko anti mi jade niso tie naa. Won ri wi pe awon akoko naa se regi mora won.
Won beere ibo ni oko anti mi lo ni akoko naa, iro lo n pa, sugbon iro re ko fidi mule. 

E je n ki n pada si odo babalawo ti mo wa. Gege bi asiri to tu leyinoreyin se fi han. Ogun owo ni oko anti mi fe fi mi se lodo babalawo kii se wi pe o fe ba mi seyun.




Iru ogun owo to fe se, iyawo re to ba loyun sikun tabi obirin to ba loyun fun un ni won ni yoo lo. Eyi tun mo si wi pe eje orun to je omo tie ni orisii eroja pataki ti won fe fi se ogun owo naa. 


Leyin ti won ba lo eje orun yii tan, iya omo naa yoo ya were tabi ki iya omo naa ku. 

Sugbon ogun owo to fe fi mi se ko pada je fun-un, nitori eje re ko ni oyun ti mo ni sikun. Ibi ni ara ti fun mi wi pe Santana gan-an ni mo loyun fun kii se oko anti mi. 

Igba ti ogun naa ko pada je, eyi lo so mi di eni ti ko je ero aye, ti ko si je ero orun. Mo kan yaju sile lasan ni ti won on fi sibi ta omi si mi lenu lai mo ibi ti mo wa.

Babalawo naa ti ni ki oko anti mi wa gbe mi, sugbon aimo ibi ti o gbe mi lo ni ko ti je ko lo gbe mi lodo babalawo.




Odo babalawo ni mo wa nigbogbo igba ti won n wa mi titi di akoko ti awon olopa fi gbe oko anti mi.

Aburo baba mi to pada sile ti lo fi ese ile to oro naa. Won si ti je ko ye wi pe kokoro ti n jefo, ara efo lo wa. Won ni ko se eto aajo kan ki asiri le tu, ki awon ti won se ise naa fi enu ara won jewo. 

Ki aburo baba mi to pada s'Eko ni oko anti mi ti jewo gbogbo ohun to sele fun awon olopaa. O ku bi ojo kan ko pe ose kan ti mo ti wa lodo babalawo ni oko anti mi mu awon olopa wa sibi ti mo wa. 

Awon olopa ilu Eko koko mu isele oro naa lo siwaju awon alase olu ile ise olopa Ipinle Ogun to wa ni Abeokuta ki won to pada siluu Sagamu. 

Awon olopaa ko baba alawo ati awon eniyan ti won ba lodo re nigba ti aburo baba mi gbe mi pada si Amuloko to wa niluu Ibadan lati lo toju mi.




Ki lo sele si oko anti ati anti mi? Iru ijiya wo lo ba pade lodo awon agbofinro? Kini mo la koja ki ara mi to ya?

N tun maa pada kan si yin. E ku oju lona!

Emi Ni Tiyin Ni Tooto,
Morufa Eko
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment