Sii Olayemi Oniroyin,
Awon Yoruba nibi taa roko ti si, ibe naa laa fabo si. Emi gan-an mo wi pe o pe mi ki n to pada wa, sugbon o damiloju wi pe e o forijin mi.
O ya, e je ka bo soju ila pada.
Ni ale to ku emi ati oko anti nile, omokunrin naa pada ba mi ni ajosepo lale ojo naa leyin ti o ti je ounje ti mo pese fun un tan.
Ajosepo to waye laaarin wa ki i se bi ti akoko eleyii to fi ipa ba mi lopo, fun rami ni mo gbe ara mi sile fun un loteyii. Sebi enu to ba ti je dodo, awon Yoruba ni iru enu bee ko le sododo mo.
Eniyan to ba da omi siwaju ti di dandan ko te ile tutu. Omo oko ti o je Buredi Agege gbodo fi esuru ranse sile. Owo ti wa lowo mi, o si tun ti se ileri lati se ohun gbogbo ti mo ba n fe fun mi.
Emi naa si ti pinnu lati tele iyanju ti ore mi gba mi wi pe ki n maa dogbon gbowo lowo oko anti mi, ki emi naa le je eeyan l'Eko ki n si le daduro. Ore mi ki i ye so wi pe: " O ri ese were nile oo bu, ologbon wo ni o gbe tie duro?"
Igba ti ile mo laaaro ojo keji, mo bere ise mi gege bi a ti mo n se. Enu ise naa ni anti mi ka mi mo nigba to de lati Ibadan.
Sugbon iroyin ti anti mi mu wa lati ile je iroyin ibanuje fun mi. Baba mi ti wa lori ibusun aisan, aisan naa si sebi eni wi pe opo die.
Won so fun anti mi wi pe ko ma je n gbo nipa aisan naa sugbon ko le fi iru oro bee sikun lai so fun mi. Mo bere si ni fokan gbadura ki Olorun ba mi fun won ni alaafia.
Leyin ose meji, mo ri eniyan kan ti mo le ran si won, eni naa n lo si ilu Ibandan. Mo fi owo die ranse sile ki won fi kun owo itoju won.
Eni ti mo ran sile ko foju kan baba mi, iya mi lo kowo fun, eyi ko je ko le fun mi labo ohun ti oju re ri nipa ilera baba mi, ohun ti iya mi so fun nikan lo wi fun mi.
O dami loju wi pe iya mi ko ni fe fi gbogbo enu soro ko maa ba bami lokan je.
Ose meji ti koja ti mo ti gba majele lati fi pa oko anti mi. Sugbon mi o pada fi majele naa sinu ounje re ni ale ojo to ku emi ati e nile.
Okan mi o gbe, ko rorun fun mi lati paayan. Eri okan ko ni je n gbadun ti mo ba se bee seku pa oko anti mi. Inu emi gan-an si pada dun wi pe mi o lo majele naa.
Ara lo ta mi ati edun okan, ibanuje ti oju mi ti ba pade lodo awon okunrin eyi lo fe mu mi ru iwa bee tele.
Leyin ose meta ti baba mi ti n se aisan nile, mo toro aye lati lo se abewo si won. Ile ni won ti n toju won, won ti ru, won o si fi bee ni okun inu daada mo.
Sugbon awon to wa nile fi ye mi wi pe won ti n gbadun ju ateyin wa lo. Won ni ti mo ba wa sile bi ose kan seyin, awon ohun ti awon so yoo ye mi daada.
Won ni gbogbo ose to koja, baba mi o le soro soke, won o le jeun daada, won o si le joko rara. Sugbon nibayii, won tile jeun, won si tile joko soro.
Emi ati won tile soro daada. Won beere nipa alaafia mi niluu Eko ati awon ti won ran mi lowo.
Mo so fun baba mi wi pe won on toju mi gidigidi gan-an ni o, ati wi pe won tun fun mi lowo ki n maa fi pamo ki emi naa file daduro lai pe.
Mo lo ose kan nile, ki n to lo ni ara won ti n yagaga to si ti mokun sii daada. Inu emi naa dun.
Emi pada siluu Eko, mo si tun bere si ni gbe igbesi aye mi lo. Gbogbo igba ni emi ati oko ati mi maa n ri ara wa, ti a si tun jo ni ajosepo to letike.
Lopo igba ni o je wi pe ile itura ni a jo maa n lo nigba ti mo ba lo gbe ounje osan re fun. Kosi si igba ti a pade ti ki i fun mi lowo gidi. Ohunkohun ti mo ba si beere lowo re naa ni i se fun mi. Awon nnkan wonyii tun fi mi lokan bale wi pe yoo mu awon ileri to se fun se.
Gbogbo bi nnkan ti n lo ni mo fi n to ore mi Tolani leti, sebi gbogbo ibere oro naa lo soju re. Inu tie naa dun nipa ibi ti oro naa yori si. Mo maa n ya lowo lati raja sori igba re nigba mii lara owo ti mo ri lara oko anti mi.
Olorun lo ni ki n gbo tie, ti mo ba ti seku pa oko anti mi, oseese ko je wi pe ogba ewon ni emi gan-an iba wa bayii.
Mo n jaye ori mi lo, anti mi o si fura. Bi awon eniyan tile ri emi ati oko re papo, won ko le fura nitori opolopo gba wi pe iya kan baba kan lo bi awa mejeeji, kosi si eni to mo wi pe ko ri bee rara.
Mo n jaye ori mi lo, anti mi o si fura. Bi awon eniyan tile ri emi ati oko re papo, won ko le fura nitori opolopo gba wi pe iya kan baba kan lo bi awa mejeeji, kosi si eni to mo wi pe ko ri bee rara.
Leyin bi osu kan ti mo ti pada siluu Eko; leyin igba ti mo lo se abewo si baba mi nile. Iroyin kan mi wi pe baba mi ti saisi. Mo sunkun, oju lohun o ran mi nise. Ojo keji re naa ni mo tun pada si ilu Ibadan. Sugbon won ti sin baba mi ki n to de. Iya mi sunkun, gbogbo ile lo n sofo.
Igba to di lopin ose, oko anti mi ati anti mi wa wo mi nile. Won lo ojo meji leyin eyi ni won pada siluu Eko. Sugbon odindi osu kan ni mo lo pelu iya mi, ko tile wu mi ki n pada kiakia.
Sugbon iya mi ni ki n ma lo ki n pada wa wo oun nigba to ba ya. Awon ebi yoku ti wa pelu iya mi nigbogbo akoko yii, emi naa ba ro wi pe boya ki n lo ki n si pada wa nigba mii.
Ipada mi si ilu eko loteyii yato, orisirisi ero ni mo n ro lokan. O ti wu mi ki n maa dagbe, ki n si maa se ise ara mi. Mo so awon oro yii fun oko anti mi, o ni ko buru wi pe oun to dara ni.
Sugbon ohun ti oun ko fe ni ki n fi agidi kuro lodo anti mi laise wi pe o ti yanda mi lati okan re. Mo gba si lenu, a si tun jo n tesiwaju.
Sugbon nigba to ya, oun kan bere si ni sele si mi: oyi maa n ko mi leekookan, a si tun maa remi lati inu wa. Nigba mii si ni yii, a maa semi bi ki n fegbe lele ki n sun jeeje. Aya maa n rin mi, eebi si maa n gbe mi.
Ohun te n ro lokan gan-an lemi gan-an n ro nigba naa. Se ki i se wi pe mo ti loyun? Sugbon ti mo ba loyun, oyun esin ni fun mi, aye o gbodo ba mi gbo rara.
Won a ni Morufa loyun fun oko anti re. Se temi o ba mi bayii? Igba ti akoko to ye ki n ri nnkan osu mi to ti o wa boro ni oju mi to mo.
O sese wa ye mi wi pe mo ti ka A B D mi debi Gbi ni bayii. Sugbon bawo ni mo se le loyin? Oko anti mi maa fun mi ni kini kan lubulubu bayii wi pe ki n fi ahon enu mi la leyin ti a ba ti jo ni ajosepo tan.
Bakan naa lo tun maa fun mi ni oori (ipara) wi pe ki n fi ra oju ara mi; oori naa ki se oori lasan. O ni awon nnkan naa wa fun idena oyun nini. O ni ti mo ba ti n lo ko ni sewu. Ki lo wa le fa oyun ojiji?
Eru n bami ki anti mi ma lo mo. Mo tete salaye fun oko anti mi ko to di wi pe awon eniyan o maa fura si mi. Oko anti mi fi mi lokan bale wi pe oun o mu mi lo ibi ti won yoo ti se oyun naa fun mi. Ohun ti oju mi ti ri seyin je ki eru ba mi.
Se ki i se wi pe asiko ti n je tan ni yii? Ko wu mi ki n tun seyun, sugbon iru oyun bayii ko ni mo n wa. Oko anti mi ni ibi ti oun o mu mi lo, titi ti won yoo fi yo oyun naa mi o ni mo rara.
Mo beere wi pe se osibitu ni, o ni kii se osibitu. Mo so fun wi pe ti ko ba ti je osibitu, emi o lo o.
O ni odo onisegun ibile ni, onisegun to gbona. O ni yoo ba mi se ti o romi lorun ti ko ni sewu leyin re. O tun towo bo apo sokoto re, o fun mi ni egberun meji wi pe ki n mu dani.
Oko anti mi da ose to n bo fun mi, o ni to ba di ose to n bo, oun yoo mu mi lo si odo onisegun naa. Enikeji ti mo tun so oro naa fun ni Tolani ore mi; mo so fun wi pe mo ti lo yun.
Mo si tun so fun wi pe mo fe lo se oyun naa ni ati wi pe oko anti mi ni o mu mi lo sibe.
Igba to ku ola ti a lo sibi ti won o ti ba mi seyun naa, oko anti mi dogbon wa gbe aseje kan fun mi ninu yara mi wi pe ki n je. O ni baba onisegun naa lo ni ki n je ki ise ti won fe se fun mi le rorun ko si le ja si ayo.
Mo gba aseje naa, inu abo dudu kekere kan ti won fi amo se ni ounje naa wa. Igba ti maa ye wo, eran adiye lo wa nibe.
Sugbon igba ti mo bere si ni je, mo se akiyesi wi pe kii se adiye, eye ni nitori pe ese re tiirin ju ti adiye lo. Sugbon mi o mo iru eye to je, mi o si le salaye awon nnkan mi to wa nibe.
Gbogbo re ni mo je tan, mo si toju abo naa si abe beedi mi.
Igba to di ojo keji, laaro ojo ti a fe lo si odo baba onisegun naa. O ni ti mo ba ti de iso nibi taa ti n taja, to ba ti se die, o ni ki n yo jade tabi ki n puro pe mo fe lo ra nnkan.
O ti salaye ibi taa ti pada fun mi. Mo wi fun wi pe mo ti gbo.
N maa tesiwaju laipe…
Emi ni tiyin ni tooto,
Morufa Eko
0 comments:
Post a Comment