Smiley face

Omoge Bora Si Ihoho Nita Gbangba Fun Olorin Olokiki Ilu Naijeria Lati Ba Sun

Oju TuFace Idibia ri owo atomo ni ilu Sapele ni opin ose to koja yii, nibi won ti n pate orin eleyii ti otin Star se agbateru re.

Sadeede lomoge kan jawo ori itage to si n bo ara re si ihoho lati dimo 2face.

Ti ko ba se ti awon osise alaabo ti won gbaa lowo mu, omoge naa ko ba ja pata ati komu re danu latari wi pe o je dodo 2face gan-an.



Ohun to wa lekenka nibe ni wi pe, iyawo 2face, Annie, naa wa loju agbo nigba ti omoge yii n bo aso sile fun oko re. Oju Annie o rerin rara; n se ni omobirin naa faju ro bi eni ti won so pa. Inu un bi sugbon ko soro. Ara n ta sugbon o mu mora. Talo le gba iru e? Annie n wo omobirin naa bi ko fada be lori danu, sugbon ko sagbara fun un. Awon Yoruba ti pari oro, won ni 'Orisa je n pe meji' obirin ko denu.

Annie
Sugbon sa, kini 'tajeeti' omobirin ti n boso sile? Se o fe 'reepu' Tuface ni abi bawo? Bi yoo tile ba 2baba sun, se loju iyawo re lo ti fe se ni? Bi ko tile tiju awon ero omilegbe, sebi yoo tiju iyawo alarede oloruka ti mbe nitosi.

Eniwee, Olayemi Oniroyin ni oruko mi, inu eje mi si ni ise iroyin wa. Sugbon ki ose yii to pari mo le bere ise orin kiko, ilu Sapele ni maa de ti bere. Ki Oluwa ran mi lowo. Amin

E ku oju lona!


Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment