
Ojo gbogbo ni tole, ojo kan ni toloun. Owo awon olopa digboluja SARS ti ilu Eko ti te awon igara olosa eleyii ti won gba wi pe awon ni won ti n finna mo papako ofurufu
Gege bi oro awon olopa, won ni awon ole yii ti ri owo bi irinwo milionu (400m) gba lowo awon ti n se pasipaaro owo ni papako ofurufu
Olori awon omo adigunjale yii to pe oruko ara re ni
Samuel Mayegun, ti inagije re si nje Asiwaju ti kabamo to si n fi ika senu to wi pe:
'kani mo ti mo wi pe bo se maa ri fun mi ni yii, mi o ba ti salo si oke okun lojo ti mo ri 45M kojo nidi ise ole jija. Won ba mi so, sugbon mo kotiikun siwon'.
Lara awon ti owo tun te pelu Asiwaju ni Biodun Adegayo, Ezekiel Anthony, Ibrahim Sado ati Femi Osiyelu.
0 comments:
Post a Comment