Yang Jinhai, omo odun metadinlogbon (27) ti binu sọ ara rẹ si ẹnu àmọ̀tẹ́kùn ninu ọgba ẹranko Chengdu to wa ni ilu China latari ironu ati ibanujẹ ọkàn nipa aye rẹ tó gbà wi pe ko ni itunmọ.
Omokunrin yii la gbọ wi pe ọ́ gba isẹ asọbode ni Goosu-Iwo Oorun ilu China. Igba to ya loni ise naa su oun lo ba tun lọ gba isẹ ni ile isẹ kan ti won ti n tẹwe. Igba to ya ni omokunrin yii tun kowe fi ise sile latari wi pe ayọ rẹ ko kun nipa igbesi aye rẹ.
Omokunrin yi ro gbogbo rẹ papọ, lo ba ku pinnu lati fi igbe aye ti ko ni itunmo se ọmọ eranko lóóre. Awon ti ìsẹ̀lẹ̀ náà soju won so wi bi ere bi awada ni omokunrin naa gun odi ti won fi yii awon eran naa ka to si sọkalẹ lọ ba awon eranko naa ninu aafin won.
Awon Amotekun bo Yang Jinhai lati fi se ounje osan, ọpẹlọpẹ awon osisẹ ọgbà ẹranko naa ti won yin orisii ibọn kan to maa n kun ni lóorun mọ awon Amotekun naa ki won to fa Yang Jinhai jade ninu ihò iku.Ẹ tun le wo fidio isele naa NÍBÍ
Fidio
0 comments:
Post a Comment