Smiley face

Ojulowo Wahala: Ajo EFCC TI Soobu Laide Bakare, Won Tun Gbe 'WANTED' Le Ori Oko Re

Awon ajo EFCC pelu ase lati kootu ijoba ti tilekun ile itaja Laide Bakare eleyii ti won lero wi pe oko re, Alhaji
Orilowo lo si fun un.

Alhaji Orilowo lagbo wi pe won fi esun jibiti kan latari ise agbase ile kiko kan, Y'hello Estate ti awon osise ile ise MTN gbe fun-un

Gbogbo dukia oko Laide Bakare ni awon ajo EFCC ti bere si ni gbese le bayii. Lara awon dukia re to ti wa ninu apo Economic and Financial Crimes Commission (EFCC) ni ile epo meji to ni ni agbegbe AJah to wa ni ijoba ibile Ibeju Lekki ati soobu itaja nla kan to si fun iyawo re.

Iroyin ti a tun gbo ni wi pe awon EFCC ti gbe "Wanted" le oruko Alh Orilowo bayii, gbogbo ara si ni ajo naa fi n wa okunrin naa bayii bi iya ibeji to ri Taye ti ko si mo eni gbe Kehinde pamo.

E maa gba wi pe Laide Bakare ti salaye lori esun yii nigba kan ri, eleyii to wi pe awon onibaje ni won fe se akoba oko oun. Ati wi pe eniyan olorun tooto ni Alh Orilowo, ti ko mo bi won se n lu eniyan ni jibiti 419.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment