Lati ilu South Africa bo silu Amerika, sebi ise aje ni ko je ki Taye-Kehin awon omo Okoye o sunle mo. Pelu atileyin egbon won Jude Okoye, P-square n mu lati ju awo orin eleekefa sita fun igbadun aye.
Gege bi Iwadii Olayemi Oniroyin, obe naa ti jina ki won so kale fun jije lo ku bayii.
Gege bi akiyesi awon oniroyin amuludun ile Afirika se woye, won ni awo orin tuntun P-square yoo tun mu won gun akaba to kan loke ninu ise orin kiko lagbaye.
Ninu awon olorin ti won gba owo to poju bayii ni ilu Nigeria ni Davido wa, Wizkid omo aye wa nibe, 2face ati Dbanj jo n le ara won ba ni.
Lara awon olorin ti won maa n fi sakasaka gba opolopo owo tabua lowo awon onibara won ti won ba fe pate ariya naa ni Olamide Mr Badoo, Timayah, Flavour, M.I, Ice-Prince, ati Iyanya.
Awon to ku ni Wande Coal, Tiwa Savage, 9ice, D'Prince ati Dr. Sid ti gbogbo eniyan tun pe ni Mr DoroLere
Sugbon bi igi ba pe igba nigbo, iroko ni baba igi. Alagbaa si ni oga awon egungun. P-square ki gba kere ju milionu mewaa (N10M) fun ode orin kan soso lo.
Awon kan naa si ni iwadii je ko ye wa wi pe won gba owo to poju lo ni ile Nigeria.
Olayemi Oniroyin naa lo n de soju iworan yin. DoroKoko iwe iroyin naa le si kan tan.
E ku mukulumukeke!
0 comments:
Post a Comment