Smiley face

Aye Akamara: Ta Lo Ge Ori Karen?

Kari aye ni won ti n se ise ibi, eyi to sele ni Soka ni Ilu Ibadan kan gbe ariwo kari lasan ni. Iwa ika inu eda, inu eniyan lo wa.

Gbogbo ibi omo adariwurun ba ti n gbe, ibe gan-an ni iwa odaju fikale si.

Ni ileto kan to n je Common ni agbegbe Backbush to wa ni St Andrew ni Ilu Jamaica ni isele yii ti sele. Ori oke kan ni ilu naa ni won ti ba oku Karen Rainford ti won ti ge ori kuro lorun re.



Enikeni ko le so eniyan kan pato to se ise ibi naa. Awon kan so wi pe oseese ki o je oko re to ko sile lo se ise ibi naa. Omo mefa ni Karen bi, sugbon merin lo bi fun okunrin ti won fura si wi pe oseese ko pa Karen.

Awon olopa n wa oko re ni iroyin taa gbo keyin. Ko si si enikeni to kofiri oko obirin tabi akoko ti isele yii waye.

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment