Ile ejo to gaju ni ilu Ijibiiti ti da ejo ewon odun meta fun olori ilu naa nigba kan ri, Hosni Mubarak latari esun jegudujera.
Mo ranti wi pe losu kinni odun 2011 mo kewi fun Mubarak nigba ti rogboyan n lo lowo ni ilu Ijibiiti.
Ewi naa ni yii:
Mubaraki O Si Foye e Le.
Mubaraki o si foye e le.
Ikà se joba fogun odun, aye o rojú.
Iye odun to lo loye ti t'ogbon bee ilu o fararo.
O gbenu dudu sise ibi.
O ledi mole gbogbo ilu n ke yeeyee.
Boo beru eniyan,
Se o tun beru oba Yaradu loke ni?
Kilokilo mo ni i se ko to jeka abamo.
Mubaraki ko gbo ikilo akewi. Ojo ti omi tan leyin eja re mo tun mu morin senu lojo kokanla osu keji odun 2011.
Mubarak, O Tan Fun O!
Mubarak se o tan o bi o tan?
Ojo mo forin si o leti o koti kun.
O wo n orun fefe o tun n pesu lole.
O tun laya-laya o tun pe akewi leke.
O saya gelete soosa o tun mo Oba Yaradu loju.
Lai s'Ogun lakaye o n feje eniyan we.
Bi o ko ranti iya aburo ti n sunkun,
Se o tun rati atunbotan?
Omi ti tan leyin eja re,
O ju pada ti o nigbeyin.
Won yo Mubarak loye nigba naa ni, sugbon lonii ejo ewon odun meta ni won fi daa lola.
Eniyan ko ni taja erupe ko gba owo okuta lailai.
Home / Iroyin Okeere
/ Ile Ejo Ti Ni Ki Hosni Mubarak To Je Aare Ilu Ijibiiti Nigba Kan Ri Lo Fi Faaji Se Ewon Odun Meta
Subscribe to:
Post Comments
(
Atom
)
0 comments:
Post a Comment