Smiley face

Rihanna Fe Ra Liverpool Pa Lai Wo Pata

Se eyin ti gbo nipa iroyin ti n fo kiri ayelukara? Abi eyin o ti gbo? Ani won ni Rihanna omobirin olorin ilu Amerika fe ra egbe agbaboolu Liverpool ti ile England pa patapata. 


O ni lati je wi pe owo buruku wa lowo bebe na. Abi eyin o mo wi pe ti eniyan ko ba ni kunkushi owo baba owo ko le ra iru egbe agba boolu Liverpool ni?

A ti wi pe omobirin naa ko mo nipa bisineesi rara. To ba je wi pe omobirin naa mo nipa bisineesi ni, Alekuso Mighty Football Club to wa ni ilu Ibadan lo ye ko lo ra.
Boolu ti awon omo Alekuso n gba o daa rara. Chai! Ori okuta ni won ti n gba boolu lojoojumo, ese won ti yi bi ese were. Ese lasan ni won fi n gba boolu ti won, ojo ti won ba jaja ri kanfaasi bayii, bi oba ni won se lori odan.

Eni lori ko ni fila loro ile aye. Eni ni fila ko lori ti o de si. Ki Edumare ba wa mu iponju kuro ni ile Nigeria. Aimoye talenti ni i sofo lorileede wa.

Sibesibe, ife Nigeria si wa lokan mi. Sebi eyin naa mo?
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment