Smiley face

Awon Omo Ile Igbimo Asofin Agba Metalelogota (63) Ti Fowo Si Leta Yiyo Aare Jonathan Loye

Gege bi iroyin to lu jade lati ile igbimo asofin agba Abuja, awon omo ile igbimo asofin 63 ninu awon 109 ni won ti fi owo si leta kan ti won ko ni bonkele lati yo Aare Goodluck Jonathan kuro loye.

Esun pataki ti won si gbe siwaju naa ni wi pe n se ni ijoba Aare Jonathan n se owo ilu basubasu lati igba to ti gori oye. Lara esun won tun ni iwa jegudujera to gbile bi owara ojo ninu isejoba GEJ.

Ohun ijoloju ibe ni wi pe, awon omo PDP bi mejo (8) kan wa lara awon ti won fi owo siwe naa lati yo Jonathan danu bi igba eniyan yo jiga lese.

Iwadii ti www.olayemioniroyin.com se fi ye wa wi pe awon omo PDP ti won fowo si leta naa se bee nitori ife okan ti won ni. Ohun ti awon n beere fun labenu ni 'Automatic Ticket' lati inu egbe PDP eleyii ti o fun won lanfaani lati pada sile igbimo asofin lai se wi pe enikeni ba won figagbaga ninu eto idibo abenu ti PDP.

Sugbon won ko ti fi oju leta naa hande pelu ireti wi pe David Mark to je olori ile yoo ba won seto tikeeti naa lati owo Aare.

Eyi tumo si wi pe ti Aare ba le seto bi won se pada si ile igbimo asofin lodun to n bo, o seese ki awon omo egbe PDP mejo naa fadi seyin ninu igbiyanju ile lati yo Jonathan.

Awon isele to n sele leyin itage oselu yii n fun Aare Jonathan ni aibale okan ati airoju-airaye gidigidi.

Sugbon sa, ka to ri ose to n bo. O seese ki oro naa ti de gbangba eleyii to sile je bakan meji: yala ile igbimo asofin yoo tesiwaju abi won yoo fa leta na ya peregede bi owo aso.

Olayemi Oniroyin ni oruko mi. Eniyan le se ise ibi kaye tun ponle nigbangba. Ika eniyan le mayeje lasan ni, orun nko?

E ku ikale!
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment