Sii Olayemi Oniroyin Agbaye
Leta eleekerinla (14) mi ni yii, eleyii ni maa si fi kadi itan igbesi aye mi ti mo ti n ba a bo fun igba die nile.
Se mo le dupe tan lowo Olootu Olayemi Oniroyin fun atileyin won lati je ki awon eniyan ri ogbon kan tabi meji ko ninu irin ajo aye mi? Titi laelae ni maa ma fi imoore mi han.
Adura mi si ni wi pe iwaju ni opa ebiti n re si, iwaju le o maa lo.
Odindi osu mefa ni won fi toju mi leyin isele to sele si mi ko to di wi pe ara mi ya tan. Nigba ti ara mi ya tan, mo tun fe e lo bi odun kan o le ki n to bo sipo daada ko to di wi pe mo n jade kiri.
Mo ti de enu bode orun, o wu Eledumare lo dami pada wa saye.
Ile onisegun kan ni won gbemi lo ni agbegbe Amuloko to wa niluu Ibadan. Baba yii lo wo mi san, ti ara mi fi ya. Igba ti ara mi ya tan ni won salaye gbogbo ohun to sele si mi.
Emi naa salaye ohun ti oju mi ri, gbogbo wa la tun bu sekun bi eni wi pe isele naa sese waye ni.
Titi di oni yii, enikeni ko le so ibi ti anti mi wa. Ohun ti won so fun mi ni wi pe anti mi sa lo nigba ti owo awon olopa ti te oko re.
Olopa gbe oko anti mi ati babalawo re lo si ile ejo. Sugbon enikeni ko le so aridaju ohun to pada sele. Gege bi oun ti mo gbo, won ni won ran won lewon odun mewaa, awon kan ni metala ni won ran-an.
Olopa gbe oko anti mi ati babalawo re lo si ile ejo. Sugbon enikeni ko le so aridaju ohun to pada sele. Gege bi oun ti mo gbo, won ni won ran won lewon odun mewaa, awon kan ni metala ni won ran-an.
Emi o pada s'Eko mo lati igba naa, Amuloko ni mo n gbe. Ibe si ni awon eniyan ti n pe ni Morufa Eko.
Mo ti to omo odun metalelogbon (33) bayii, igboro ilu ibadan ni mo si n gbe. Mo ti lo kawe olopin ose lati ni iwe eri NCE lowo. Ni agbegbe Oremeji to wa ni ona Sango ni mo ti gbe n ta oti waini ati awon elerindodo.
Mo ti yi oruko mi pada lati igba ti mo ti kuro ni Amuloko, ti mo si pada wo inu igboro Ibadan wa; oruko tuntun mii ni mo n je bayii. Mo si ti gbiyanju lati ni oko ni awon akoko kan leyin ti mo de sigboro ilu Ibadan.
Emi ati oko mi tile ti gbe bi odun meji ka to tuka, onikaluku si ti wa lori owo ara re. Mi o ti bimo, mi o si loko lowolowo bi mo n se ko leta mi yii ranse.
Sugbon igbagbo mi ni wi pe ile Olorun kii su. Nigba ti akoko Oluwa ba to, ohun gbogbo yoo tun dun ju bayii lo fun mi.
Awon Yoruba ni ogun omode ko le sere fun ogun odun; o n se mi bi ki n maa ti lo. O wuni ka jeran pe lenu ni sugbon onfa ona ofun ni ko je.
Ayo ni a maa gburo ara wa, ibanuje ko si ni wole enikeni.
O digba kan na!
Emi Ni Ti Yin Ni Tooto,
Morufa Eko
Morufa Eko
Adupe popo lowo ogbeni olayemi oniroyin fun anfaani ti e funwa lati ba iroyin dopin,edumare o tunbo maa ranyin lowo,aunty morufa eko eku ajasegun,eku akoyo,olohun o maa fi iso e so enikookan wa. #omoade lon kiyin
ReplyDelete