Igbeyawo Oloruka |
Olayemi Oniroyin, sebi awon Yoruba loni eran taa ta ta o to, ni deran onidin. Leyin bi osu mefa ti iroyin ti gbe mi lo si ilu South Africa nibi ti iya eni odun mokanlelogota(61) ti di iyawo asesegbe fun omokunrin eni odun mejo, mo pada sibi ti mo fi iroyin ti si lati mo ibi oro de duro lori igbeyawo to se gbogbo aye ni kayeefi.
Fun anfaani awon ti won sese n ka iroyin yii fun igba akoko. Sanele Mesilela eni odun mejo lo sadeede fi oruka si Helen Shabangu lowo eni to ti bi omo bi marun-un gege bi iyawo re tuntun ni Tshwane ni ilu South Africa.
Gege bi iwadii se so, won ni fife ti Sanele fe iya agba yii waye latari asotele baba re ko to di wi pe o ku. Ati wi pe majemu kan mbe ti baba re ti se sile, eleyii to je wi pe lara ileri majemu naa ni fife ti Sanele fe iya agba naa.
Aimoye asiri ni idile omo odun mejo yii fi owo bo mole ti won ko fe ko lu jade nipa ohun to se okunfa igbeyawo kayeefi yii gan-an. Sugbon ominu ko ye e ko awon eniyan, opolopo si gba wi pe ohun ti mbe leyin Ofa j'Oje lo.
Olayemi Oniroyin pada lati lo topinpin bi toko-taya yii se n se leyin igbeyawo won. Bi o tile je wi pe won ko lati so fun oniroyin boya ajosepo loko-laya n waye laaarin awon mejeeji, sugbon ohun to daju ni wi pe awon mejeeji si n gbe papo gege bi toko-taya.
0 comments:
Post a Comment