Ninu ipada eleyii ti o pari ni nnkan bi ago kan oru koja ogun iseju ojo Aje oni yii(20/1/2014) ni won ti se ipinnu lati fi Alhaji Adamu Mu'azu ropo ipo alaga eleyii ti Alhaji Bamanga Tukur ko iwe fi sile ni Ojoru to koja.
Bi o tile je wi pe iwadii abenu fi ye wa wi pe Mohammed Wakil ni eni ti Aare fara mo ko je alaga agba egbe naa sugbon eleyii ti ko si ni ibanu pelu ero ati ife awon gomina ti n won pejo sibi ijiroro naa.
Leyin opolopo atotonu, Alhaji Adamu Mu'azu ni Ifa pada mu gege bi alaga tuntun egbe PDP eleyii ti won ko ni pe kede re fun araye laipe.
0 comments:
Post a Comment