
Bi Gomina Abiola Ajimobi ti Ipinle Oyo se n gbaradi lati koju Rasheed Ladoja pelu Alao Akala ninu eto idibo odun ti n bo lona , bee gele ni Aregbesola ko fi oju ire wo Omisore to je alatako kan pataki lati inu egbe PDP ni Ipinle Osun. Agbenuso fun Gomina Aregbesola nipa eto iroyin, Ogbeni Semiu Okanlawon ti se apejuwe Omoisore gege bi agogo ti n pariwo lasan lai ni ohun kan to ni itunmo to fe se fun awon ara ilu. Oro yii lo je jade nipa awon ipade ita gbangba eleyii ti Senator Iyiola Omisore ti bere ni Ipinle naa lati fi ero re han gege bi olodije fun ipo Gomina labe egbe oselu PDP.
0 comments:
Post a Comment