Smiley face

Aare Uganda Fi Ose Yi Aare Goodluck Jonathan Nita Gbangba

Awon Yoruba ni ti iya nla ba gbe ni sanle, kekere a tun maa gori eni. Aare ile Uganda, Yoweri Museveni lo maa fi koko oro ti n ba awon ara ilu re so sile lo ba bere si ni fi ogbon ranse oro abuku si odindin Aare ile Nigeria to je Alagbara ile adulawo pata.

Oro to so ni yii nigba to n ba awon ara ilu re soro:



"I have never called the United Nations to guard your security. Me, Yoweri Museveni to say that I have failed to protect my people and I call in the UN….I would rather hang myself,"

Aare ile Uganda ko dake sibe o, e tun gbo ohun to so.

"We prioritized national security by developing a strong army otherwise our Uganda would be like DRC, South Sudan, Somalia or Nigeria where militias have disappeared with school children.

It would be a vote of no confidence to our country and citizens if we can't guarantee our security, what kind
of persons would we be?"

E ri wi pe Olorun fun maanu yii loro so gan-an.

Sugbon sa, e ti e duro na, nje a le so wi pe o riso tabi radarada ni oro re?
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

2 comments:

  1. O fe riso pa ni. Ododo oro lo so yen o. Ijoba ti ko ba le pese abo to daju fun ara ilu o ti fidi remi. Ti iru ijoba bee ba nitiju,nse lo ye ko ro ara re loye jeje.

    ReplyDelete
  2. Otito oro bi isokuso ni. O ri so gan ni

    ReplyDelete