Smiley face

A MAA KU SI WON LORUN LOLA NI - OSAZE

Olukoni egbe agba boolu Super Eagles ti ile Nigeria, Stephen Keshi ti so ni aaro yii wi pe ki gbogbo omo Nigeria lo mokan bale nipa ifesewonse ti yoo waye lola laaarin Nigeria ati Argentina.

Olukoni yii se alaye fun awon oniroyin nibi won ti n gbaradi ni ilu Brazil wi pe gbogbo eto pata lo tito, awon si ti se atunse si gbogbo kudiekudie awon pata.

Osaze naa ba awon oniroyin soro. Ninu oro Osaze, omokunrin naa bere lowo awon oniroyin wi pe se won mo Patricia Etteh. Awon oniroyin ni awon mo Etteh. Osaze ni ti won ba ti mo Etteh, o ni ki won gba wi pe awon maa dete si Argentina lorun ni. 'A maa ku si won lorun ni lola yen' Osaze lo so bee.

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment