
Leyin tí wọn ti dé Davido lade ọba orin ilẹ̀ adúláwọ̀ fún ọdún 2014 níbi àmì ẹ̀yẹ BET to wáyé ni L.A ni Ilu Amerika ni awon oniroyin amuludun kò ti jẹ ki ọmọkùnrin naa gbadun mo o. Joojumo ni wọn gbe kamera si ẹnu ọ̀nà ile re lati bèrè ọrọ lọ́wọ́ rẹ nipa bi inu rẹ se dun to pẹ̀lú ami eye tuntun ti won fi goolu se to gba.

Davido ti n pate orin kiri ni ilu Amerika sáájú ọjọ ti won fun ni ami eye olokiki to gba. Sugbon ohun ti a tun gbọ ni wi pe ode orin re ti bẹ̀rẹ̀ si ni kun akunfaya bi igba ti Jesu ñ waasu ni Jerusaleemu leyin to gba ami-eye tuntun naa tan. Opolopo awon eniyan ni won ja tikeeti lati wo ojú rẹ̀ lasan, aimoye lo si wọ baalu lati ilu Canada wa wo Skelewu ti won jo ni ilu Amerika.

Awon oniroyin bi nipa bawo lo se ri okiki re ti n kan kiri Ilu Amerika gẹ́gẹ́ bi oba orin ile adulawo ti BET fun odun 2014.

Ohun ti David so ni yii.

" Iyanu ni Olorun mi fi se, ati wi pe asese bere ni. Aseyori mi kii se fun emi nikan bikose fun Nigeria ati ile Adulawo lapapo. Awon nnkan to n sele yii n se apere wi pe orin Naija ti ridi mule laaarin amuludun agbaye."

Eni to wu Edumare lo n gbega. Asiko omo Adeleke re e. Kabiesi oba orin tuntun ile adulawo.

Osu kokanla odun 1992 [21-11-92] ni wọn bi David Adeleke si Atlanta, Georgia ni ilu Amerika. O ti bere eko re ni ile iwe Oakwood University nibi to ti n ko nipa ìmọ̀ ìsàkóso okoowo sise ko to wa pada wa si Babcock University to wa ni Ipile Ogun lati wa pari eyi to ku nínú iwe kíkà re.

Onisowo nla to laamilaaka ni Deji Adeleke to jẹ bàbá re. Oluko ile iwe giga si ni Vero Adeleke to je iya re ko to di wi pe olojo de. Bi o tile je wi pe Dafiidi ti n korin tipe lati kekere sugbon odun 2011 lo so ijo dowo to si mu ise orin kiko nibaada.

Odun 2012 lo ju awo orin re akoko sori igba eleyii to pe ni Omo Baba Olowo. Ati igbayii wa ni irawo re ti duro soju orun. Irawo re tan o mole bi osupa. Osupa re si mole, o mole ka gbogbo aye. Igba ti Dafiidi yoo fesi oro lori irawo re ti n tan bi osupa, o ni; "Edumare Lo So Aye Mi Di Iyanu, Agbara Kosi Lowo Eda Eniyan".


Olayemi Oniroyin, ibi ti maa ti duro ni yii.
Maa tun pada fun akotun iroyin to kun fofo.
Ramadan Kareem fun awon Musulumi gidi.
posted from Bloggeroid
0 comments:
Post a Comment