Smiley face

Wa Agbara Láti Mu Àlá Rẹ Sẹ

Wa Agbara Láti Mu Àlá Rẹ Sẹ

Wa agbára láti mu àlá rẹ sẹ. Ma si jẹ ki ohun to n sẹlẹ̀ si ọ lọ́wọ́lọ́wọ́ ba èrò rere ọkàn rẹ je nípa ọjọ́ ọ̀la rẹ. Oni le buru sugbọn ohun to daju ni wi pe, ọla yòó dun joyin lọ. 


Ma banujẹ nítorí wi pe awon kan ti lọ síwájú sáájú rẹ tàbí ohun to n fẹ ko ti tẹ̀ o lọ́wọ́. Akoko onikaluku ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni. Ba onire yọ, gbàgbé àsìse àná, máa dunnu nígbà gbogbo, rẹrin, jẹ ki ọkàn re kún fún ayọ̀ repete nítorí nínú èyí ni ìgbéga rẹ wa.

Wa gbọ, bi o kò ba le fo bi ẹyẹ asa; gbìyànjú ko ri wi pe oun sare. Bi o si le sare, maa rin. Bi agbára re ko bá le rin maa rakoro. Labẹ bo ti wu ko ri, ri daju wi pe o duro soju kan bi adagun omi ninu igbe aye rẹ.

Ma fi òní dọla. Gbadura nigba gbogbo si Olorun rẹ , ko si maa soore bi ipa re ti mọ.

Olayemi ni oruko mi, ilu Nigeria ni mo n ja fun.
Mo wa ki yin fun osu alayọ tuntun.
Gbogbo igi t'elegbede ba fọwọ́ ba pata ni i dun.

E ku ayọ osu tuntun

#HappyNewMonth.

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

1 comments:

  1. O seun pupo olayemi,opolo re ko ni dojuru.amin

    ReplyDelete