Nibayii, egbe PDP ti yan igbimo elenu meta eleyii ti olori ile igbimo asofin agba, David Mark ko sodi lati gbera lo si Ipinle Ogun l'Ojobo ti n bo yii (24-09-14) lo ba Gonima Ipinle Ogun nigba kan ri, Otunba Gbenga Daniel.
Koko ise won naa ni lati fa oju gomina naa mora lati pada sinu egbe alaburada. Gege bi oro oludamoran Aare Jonathan nipa oro oselu, eni to tun wa lara igbimo ti won yan, Prof. Rufa'i Alkali se so, o ni Aare ko fe wole ipo Aare ni Ipinle Ogun nikan lodun 2015, sugbon idunnu Aare ni lati ye aga mo Ibikunle Amosun nidi.
Ona kan soso to si le mu eleyii rorun ni lati pe OGD, eni to ti darapo mo Labour Party pada sinu PDP pelu gbogbo awon alatileyin re.
Lara eni to tun wa ninu igbimo naa ni igbakeji alaga egbe PDP lapapo, Oloye
Uche Secondus.
Ogbeni Dimeji Bankole naa ni a gbo wi pe egbe PDP fe lo lati gba ipo Ibikunle Amosun lodun 2015 gege bi gomina tuntun.
Subscribe to:
Post Comments
(
Atom
)
0 comments:
Post a Comment