Olayemi, emi o ni mi o k'ewi mo.
Awon omo araye lara won kotito oro gidi.
Iro pipa o si b'ewi mi mu.
Ti mo ba darin ibi niwon fi n su mi.
Ti mo ba kilo iwa ibaje won a laseju mi po.
Mogbiyanju ki n wedo lai fara kanmi, iro ni mo pa.
Mo rin jelenke bi kori o ma mi lorun, sibesibe lori ofo ni.
Ohun to gbayi bi iro o si laye.
Otito lo doja to kuta.
Olayemi, emi o ni mi o k'ewi mo.
Awon omo araye lara won kotito oro gidi.
Isu nikan ko niyan.
Bi koko ba n fe ni le fe e, awujo kondo laagbodo de.
O ti waye kaluku ti mo fi dakeenu.
Alaye mi ti ye onilaakaye ti mo fi dake lai pede.
Orin nbe nile to ba je torin gidi.
Asayan ede mo gbesun asodun ko rara.
To ba jo bi iro Abiodun ni ke e bi.
Abiodun Olanrewaju ti di milonia ota n pegan.
Eko l'Abiodun n gbe, ori omi lo kole si.
Ise Kontirato l'Abiodun n se.
Eniyan ti n r'Eko e ba n k'ore mi, oko Arike.
Eni Olayemi Oba Akewi mo won leeyan pataki.
0 comments:
Post a Comment