Smiley face

Otito Ti Jade Ninu Iwe Iroyin Tribune Nipa Wale Dada TheGood

Felefele Laye! Eni ore da ko ma se binu sebi abinibi gan-an dani. Yato si wi pe FELEFELE LAYE je okan lara gbajugbaja fiimu agbelewo lati owo Adewale Dada TheGood, o tun je arojinle ise opolo eleyii to n fi iwa omo eda eniyan han lawujo. Sebi aye o le, awon omo eniyan lo so ile aye dogun.

Nibayii, awon kan ti lo n kede wi pe awada lasan ni ero TheGood lati soju awon eniyan ti won gbe ni agbegbe Sango Ota ni ile Igbimo Asofin Ipinle Ogun lodun 2015. Won si n se eyi lati bu omi tutu si okan awon eniyan.

Ninu iwe iroyin Tribune ti ile Nigeria to jade lonii [12-10-14], oludari ile ise God's Chosen Productions salaye wi pe aheso lasan ni oro naa. Agbaoje sorosoro to kawe gboye nipa Igbohun safefe ni Moshood Abiola Polytechnic, Abeokuta fidi okodoro oro mule fun awon oniroyin.

"I am not stepping down for anybody. It was really funny hearing in some quarters about my political ambitions despite my obvious moves and wide consultations within and outside the state. Am for good governance and quality representation for the people." Alaye Ogbeni Wale.

Laipe yii ni awon eniyan agbegbe Sango Ota ni Ipinle Ogun gbe Wale Dada soke gege bi asoju ti won fe nile igbimo asofin ipinle Ogun lodun 2015. Aseyori yii si le je ohun ti awon kan n gbiyanju lati dawo lule nipa aheso ti ko lese nile rara. E le ka iroyin naa nibi: www.olayemioniroyin.com/2014/09/won-ti-gbe-adewale-dada-soke-ni-ipinle.html?m=1

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment