Niwon igba to je wi pe pupo awon eniyan dudu ti won gbe ni ilu London lo je omo Naija, boya eyi ni Aare Goodluck Jonathan ro papo ti ariwo ipolongo re fi rinle bi owara ojo ni Ilu Oba Elisabeeti.
Oke ni won gbe oruko Aare Goodluck Jonathan si lara awon oko akero ilu London lati fi se ipolongo eto idibo odun 2015 eleyii ti yoo waye ni ilu Nigeria.
Yato si eyi, awon igberiko ni ilu Nigeria ni won ti bere si ni ko iresi Goodluck wo bayii lati pin fun gbogbo awon oludibo pata.
Iresi Goodluck dun, ko si ni okuta ninu rara. Awon omo iresi naa tobi daada bi ata shombo ni won ri eleyii to mu yato si awon iresi ti won ta loja. Bakan naa lo tun gbe to je wi pe ti eniyan ba da agolo kan si inu omi bi agolo meta ni i ri to ba jina tan. Oju iresi naa pon resuresu bi osumare eleyii to fi han wi pe 'fitami' inu re kun fofo bi ataare. To ba jina tan ni i di funfun kiniwin bi lekeleke. Eniyan ko ni je iresi Goodluck leekan ki eni naa ma tun beere si.
E joo, se won ti ko iresi naa de adugbo yin?
Subscribe to:
Post Comments
(
Atom
)
0 comments:
Post a Comment