Smiley face

Kini Ipinnu Funke Akindele Omo Ogoji Odun Nipa Igbeyawo?

 
Leyin igbeyawo Funke Akindele pelu Alhaji Kehinde Oloyede eleyii to fori sanpon. Opolopo awon ololufe Funke ni won da Jenifa lebi nipa sise igbeyawo pelu okunrin oniyawo pupo naa. 

Isele naa dun awon ololufe Jenifa gidi eleyii ti won tara, ti won si n so wi pe asise gbaa ni igbese Funke je. Lara awijare won ni wi pe elesin Kristeni ni Funke, ki lo mu lo fe Alaaji oniyawo repete? Se tori wi pe ko tete ri oko fe lo mu wu iru iwa bee ni abi bawo? Sebi awon Yoruba ni a-pe-ko-to-je kii je ibaje ni won wi? Ki lo mu Funke lati ma le mu suuru leyin aimoye odun to ti n duro de oko gidi alalubarika ti yoo ba kale?


Nibi ti awon kan ti n da lebi ni awon kan ti n ki lokan ti won si ni ko tuju ka wi pe Olorun oba lo ni deede lodo.

Nibayii, ko si aridaju wi pe oro oko nini tabi igbeyawo tile wa ninu ipinnu oserebirin eni odun mokandinlogoji (39) ti gbogbo eniyan mo si Jenifa. Eleyii ko si rekoja awon iriri orisirisi ti omobirin naa ti ri pelu awon okunrin lati eyin wa.

Sugbon ohun kan to ru mi loju julo ni wi pe, awon isoro ti awon oserebirin onise tiata n koju nipa igbeyawo won, se awon okunrin ti won n fe ni ka da lebi ni abi awon oserebirin onitiata wa?

Opolopo won ni ko ri ile oko gbe, odun meta-meta ni awon kan fi n paaro oko bi eni n paaro aso nigba ti awon kan ko tile setan lati loko rara.

Kini ni isoro to maa n tun awon igbeyawox won ka?
Awon aworan tuntun Jenifa 
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment