Smiley face

Ọjọ Ti Wọn Bi Misao Okawa Ni Ilu Japan Ni Won Bi Omoiyashina Ni Ilu Nigeria

Iya arugbo eni Odun metadinlọgofa 117 se ojo ibi lonii ni ilu Japan

Ọgbọn ti Ọba Adaniwaye fi mu ojú ọ̀run duro lai ri òpó kankan, ko si eni to ye. Oba Ajidara nikan lo le sohun to koja oye eda.

Idi ni yii ti oro rẹ fi jẹ iyanu!

Iwe akosile Isẹlẹ gbankọgbi ti a mọ si Guinness World Records ti se afihan Misao Okawa, omo ilu Japan gẹgẹ bi obirin to dagba ju lọ lagbaye ni odun 2013. Opolopo awon eniyan ni won ko lero wi pe iya arugbo naa tun le sodun tuntun lẹyin ìgbà ti okiki iya naa ti kan kiri agbaye.

Gege bi orin Oba Saheed Osupa, " Olorun lo mo ibi ẹmi gbe le pin, eniyan ò mọ ibi ẹmi gbe le pin".

Bi ere bi awada, odun mii tun ba iya arugbo yii loke eepe pelu bo se pe eni odun metadinlogofa (117) lori erupe ile.

Gbogbo ebi ni won pejo lati sojo ibi iya yii lonii ni Ilu Japan, eleyii ti ayeye ojo ibi naa si ti wo inu iwe iroyin agbaye.

Iwadii fi ye wa wi pe ojo karun-un osu keta odun 1898 ni won bi Misao Okawa. Odun 1919 lo se igbeyawo. Edua oke fun lomo meta, awon omo naa si ti ni omoomo.

Awon oniroyin beere asiri emi gigun iya yii, ohun to so ni yii:
"Asiri emi gigun ti mo ni je okan lara awon nnkan to sokunkun si mi, ti mi o le salaye re"

Ojo Karun-un osu keta odun ni won bi Misao Okawa si ilu Japan.
Ojo karun-un osu keta odun yii kan-an naa ni won bi Olushina Olabode OmoIyashina ni ilu Nigeria.

Oju ojo ilu Jepan n sare ju ti Nigeria lo ni ojo karun-un fi bo soni(4/3/15) ti won fi n sariya. Toba di lọla (5/3/15), Ijo idunnu ni Omoiyashina yoo maa jo nitori wi pe ayeye ọjọ ibi ti e o sẹsẹ bẹrẹ ni. Mo gbadura wi pe ki Omoiyashina naa o pe laye bi Misao Okawa ti ilu Japan. Ko dagba titi ki oruko re naa wonu iwe akosile Guinness World Records. Amin.  
Omoiyashina
Omoiyashina je sosroso ori redio ti ile ise SPACE FM to wa ni ilu Ibadan


Ohun ti iwe iwe iroyin TIME ti ilu Amerika gbe jade ni yii nipa Misao Okawa

Misao Okawa was born on March 5, 1898

The world’s oldest person has lived through two World Wars and the invention of the first airplane, but it doesn’t seem like a long time to Misao Okawa.

“It seemed rather short,” Okawa said on Wednesday, the day before her 117th birthday, the Associated Press reports. When Okawa was asked about the secret to her longevity, she said nonchalantly, “I wonder about that too.”

Okawa was born in Osaka on March 5, 1898 and was recognized as the world’s oldest person by Guinness World Records in 2013. She has slowed down in recent months but still eats well and is healthy, according to her Osaka nursing home.

She married her husband, Yukio, in 1919, and has three children, four grandchildren and six great-grandchildren. Her husband died in 1931.

Japan has more than 58,000 centenarians, more than any other country in the world.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment