Smiley face

Ọlayẹmi Mo Rántí Bangbade Ọmọ Ajisafẹ.



Ọlayẹmi mo rántí Bangbade ọmọ Ajisafẹ.
Omo Ajisafẹ re Ibadan lati ilu Ìwó.
Bórí ẹni ba setan àá gbeni a ti ni wọle owó.
Òòsà ti ò gbeni a ki i pe lèèwò.
Bangbade tori ajé wọlu Ibadan, ilu olokiki nla.
Ilu-ẹ̀bá-ọ̀dàn to dilu nla.
E maa fìlú Ibadan welu Ìlá.
Ibadan lọmọ arogun la.
Omo agbọ́sásá ogun duro dogun.
Omo agbọ̀sàsà ogun sàyà gbangban
Jogun–o-mi, joojumọ niwon n roju ogun nile tiwon.
Ilu to gba onile to gba alejo.
Teru tọmọ gbogbo won ni won rọdun se.
Àgbàlagbà ilẹ̀ bi orileede ibomii ni.
  

Kékeré ni mo kere ni mo mọ Bangbade.
Ọdọmọde tórówó lògbà to tun un wọsọ ire.
Tówó ba n sọrọ ki táláká o pẹnu mọ.
Ọjọ ori kọ legbọn owó kii sàbúrò.

Bọmọ kekere ba lówó ka pọnle.
Bi mòjèsín ba ríre ra lọjà ka yee pgan.
Ẹ wa wo bọi ti n gaasi ọrun si baba wọn.
Bangbade ọmọ Ajisafẹ ti ri mọ̀ní lògbà.

Bi Bangbade ba yàka si baba won.
Won a bóhín sọmọ Ajisafẹ.
Bo ba n mọ won loju.
Won lara ni i da, won lara pọ lọwọ iru won.
Eyi ni mori lọla fi n wumi pupọpupọ.

Olayemi bi n ba ri Bangbade maa bẹ orí.
Ko jẹ n rafẹ se bi ọmọ Ajisafẹ.
Ma wale Afuwapẹ ko dakun ko maa fọrọ mi sẹfẹ.
Ko jẹ n rówó ki n rohun gbéra.
Ki n maa ti sanmọri lògbà àgbà.

Igba ìgbà re kọja
Igba ìgbà bọ soke.
Igba igba ìgbà lẹgbendinlogun wa bọ soke mọ́lẹ̀ kedere
Mo kuro ni mọ̀jèsìn wa toju bọ.
Òye ọrọ wa n ye mi bo diẹdiẹ.

Olayemi morí Bangbade omo Ajisafẹ mo tẹsẹ mọrin.
Eniyan to ti n fi mẹsi ọlọyẹ rin tẹlẹ ri.
To wa dẹni ti n tasẹ rin kiri.
Awọn olòsì eniyan wọn a tun maa wọsẹ n lẹ rin.
Mo sare bẹ ori ko fun mi nipin temi, ìpín ire.
Mo kọ Gbangbade mo kọ ayé òsì.
Òsi ni i jẹ ‘tani-mọ-ọọ-ri’.
Owó ni i jẹ ‘iyekan-mi-ni’.
Ijo ajumọjọ wa dijo adajo.
Bangbade omo Ajisafe wa deni òsì n ba lo.

Olayemi ọrọ ru mi loju mo to n yèyé mi lọ.
Sebi adan niyekan òbẹ̀
Òrófó lo le fọhun fàwòko.
Mọgba lo le bẹ Sango lọwẹ.
Bẹẹ ba régúngún ẹ beere lọwọ Alapinni.
Yeye ti mo ni lalabaro ni yẹwu.

Njẹ ẹni ti n náwó se wa pada deni ti n nara?
Eniyan ti ti n rin irin ọla se wa pada wa tosi?
Ọlọgbọn a tun ma pada domugọ bi?
Oro ree Yeye ẹ fun mi lálàyé ọrọ gidi.
Yeye n salaye ọrọ o n fi ìrírí ayé han mi
O ni bọmọ araye báyó báyọ́ titi.
O ni ti won ba yọ titi ti won ba da lápá won layọ ni.
O ni bi abilekọ ba sòwò àgbère titi  baye ọmọ rẹ jẹ to tun wa  ran ọkọ rẹ lorun, won l’èsù ni.
Esulaalu onile orita òkò.
Isẹlẹ ko ni sẹ kọmọ araye ma rin-in ran mọ.
Won sọ okodoro ọrọ nu ẹtan ni won n da bora wọn.

Bẹẹ eyi taa fi n sera wa laa ba mojuto.
Èpà to n paja lọrọ o ye.
Se tajá bá kú èpà ò ní rọ̀run ni?

Yèyé lo un mọ ọmọ Ajisafe nigba o wọlu Ibadan.
O lọkọ̀ ti n relu àwọn Àgànyì lọmọ Ajisafẹ n tẹẹle.
Ohun gbogbo ti won ba ti gbede ni won fi n sowó.
Alajapa o lọja kan pato, to ba ti baje abusebuse.
Diẹ lẹwu tounje ba ti desalẹ ikùn.

Nilu awon Aganyi ni Bangbade ti ko alawo ire.
Sebi ori lo kun un gbere e ko ni.
K’Ẹlẹda jẹ ka rire mubọ ọja.

Wọn lọkọ̀ àlòkù n wole silẹ Sàró.
Ori omi ni n ba wọle lati ilu ọba.
Aloku eebo ti won pe ni tòkunbò.
Bangbade lo un o lowo da ni.
Won ni o fowo pamọ ko fọmọniyan se.
Otitọ pon ni le ju ẹwu ẹtu lọ.
Won ni bi o ba bọmọluabi jẹ ni o jèrè to pọ.

Meji lọkọ̀ ti Gbade kọ gbe wọlu.
Ìgbà o pawó o tun gboko mii lọ.
Ko yẹ àdéhùn rara, bo ti n pawo ni dawo pada fun onitibi.
Ìgbà n yi pada, omo Ajisafe n rowo safẹ.
Ohun gbogbo n lọ ni mẹlọmẹlọ.
Bangbande ti n fi mọtọ sẹsẹ rin.

Idi ọrọ wa ree, ẹ fara balẹ kẹ ẹ maa ba soye nu.
Ogun to pa akọni-ogun ni mo logun nla.
Eyi to pa Ọjedokun ọmọ iya lagbọn lo jẹ n se gaaya.
Adia fun, nifa ta a di fẹni kan ri.
Iriri ni babalawo fi n sakawe ọrọ.
Ohun to fa sababi ni yeye to bi mi fi fidi oro mulẹ ni gidi.

Ọjọ mo fọwọ légbá funfun ni mo rilẹ omi.
Ọjọ palanba ọlọsa sẹgi ni mo mọ peeyan nii bẹ labẹ ẹku kii sòkú.  
Ọjọ iya wọ mi mọra kọ mi lọgbọn, lọgbọn mi koja kọbọ kan.
Ìgbà ọrọ ye mi tan ni mo wi ìgbà ọrọ lete lai sọrọ.
Mo sebi ọrọ làgbà fi sikun-un sọrọ.
Bi ọrọ ba ruju oro lagba fi tọrọ se.
Ọlọgbọn lo ye aabọ ọrọ ò to fomugọ.
  
Iya ni ki n gba eleyii yẹwo.
Yeye ọmọ Bolanle asọrọ tiyetiye.
O ni to ba ye mi ki n dakẹ ẹnu.
O ni to ba rújú ki n se beere wo.

O ni ohun ti n ba fokòó mi ko jọ.
Ohun ti mo ba fìgbà mi gba.
O ni ohun ni o satọna ìgbà tágbà mi o lo lori igbá.

Iya lọ́rọ̀ nini yato sówó nini.
O ni ibi a fowó si, fowó se ni fáàlà ẹni han.
Iya lolòsì eniyan a ma lówó lọ́wọ́.
Kọọkan si le sàgbà ọlọ́rọ̀ lóòórọ̀ pùtù.
Sebí ohun ti won fowo se gan-an lotitọ ọrọ gidi.

O ni ọjọ ti mo ba rẹni to mu ọgọrùn-ún naira dani.
To tun fi ba won ko ọgọrùn-ún  ìrégbè jọ.
O ni bo ti wu ki won o pẹ to òsí a ba won lo ni ikẹyin.

O ni se mo wa ri ọlọ́rọ̀
O ni ọgbọn ori won  kaa si kan ni.
O ni gbogbo owó ti won ba na, ‘owó ànábọ̀’ ni.
O ni bi won o figbìn won ránwó nisẹ.
Wọn sọwọ́ dẹrú ti n sisẹ́ tọ̀sán tòru.
Wọn pàjùbà gbọ̀ọ̀rọ̀ fájé ko maa ribi sun lágbàlá.

O ni bówó níná se jẹ koko bẹẹ nìgbà lílò se pataki.
O ni bi n ba ji laaarọ ki n to sun lalẹ.
Ki n boju weyin kin wo ohun mo gbóòjọ́ mi se.
O ni ti mo ba yin ara mi o ni ọlọgbọn ni mi.
Bẹẹ mi o nipẹ  dọlọ́rọ̀ bo dọla.
O ni tinu mi ba ba jẹ a jẹ wi pe mo sèrégbè.
Ki n yara ki n satunse.
Òsì kii ba ni lagbalagba kekere ni ti n tan mọ ni leti asọ.
Olayemi, iya nko mi lọgbọn amọdọla.
O ku loju ọgbọn ti n sọni dọlọla.
Ọgbọn a-mu-sola ko yato sọgbọn a-mu-sogo.
Eyi a-mu-soogun ko le gbeni depo ọlà digi.
Eniyan tí ò kọgbọn gidi n se ni won n takete si imọlẹ ọlà.
À séè ninu ọpọlọ dudu nìsẹ́ ti n suyọ .
Igbeyin-ingbeyin ni mo dirọ móye àgbà.

Bi o ba si t’iya mi ni, iya abiye.
Emi o ba mọọ wi pe: olòsì eniyan ati olówó, ori ni i dawon bo ti fẹ.
Bẹẹ Edua oke kii sebi,onikaluku lo mọ ohun ti n ro lọkan.
Igbesi aye ẹda mbẹ lọwọ onikaluku won.
Bori ẹda ba buru ẹ yee dajọ mọ Oluwa ọba mọ.
Ori ni mo pe ohun gbogbo a fi ìgbà ti iya fẹnu gbongbon ọrọ le lẹ.
Ohun to fa ọkà te e denu ọká.
Ohun to sọ oloogun dolójo.
Ohun to se bọrọkini to fidi alai ni nnkankan:
Oro ree iya n tu pẹrẹpẹrẹ ọ̀rọ̀ ọ́ọ̀ bọ̀.

Bi igi alàkọrí ba ruwe won ma sapa gan-angan.
Won a gbàgbé ìyà ana won ma jùpá sódòdó ti wọn ọn bomi won.
Eniyan to lówó ti o mòwò, owó won kii pẹ tan.
Bówó ba mówó wole a tun un mu ròde òwò ni.
Ẹni so ìmọ̀ àgbà mọdi ni i kọgbọn ojoojumọ.
Ọgbọn ojoojumọ nii mu babalawo difa ojoojumọ.
Ọgbọn ojoojumo ni muni leke tana buse.

Iya ti mo wi o dakẹ ẹ tun gbọ un to n pe lédé gidi.
O ni ohun ti n ba fokòó mi ko jọ.
Ohun ti mo ba fìgbà mi gba.
O ni ohun ni o satọna ìgbà tágbà mi o lo lori igbá.
Mo ni se looto lo ri?
Iya ni bẹẹ ni, olosi eniyan kii pe lórí àtẹ iyì.
Gbogbo owó ti Bangbade ri aye lofi  jẹ.
Ọkan Gbade ọkan n’Ibadan nígbà o lo sanmọọni.
Olòsì eniyan o mọpe biri layé, aye o tan lọ bi ọpa ibon
Owó tórí lo fi seré folórin.
O ba alagbere dòwòpò o gba ipo kinni.
A nawó bi ẹlẹda nígboro.
Ati ohun tótọ́ ati ohun ti ò tọ́ lọmọ Ajisafe fi se faaji.
O sọ asiko nu ko ìpín òwò fẹ́nìkan.
Àkàbà àgùndolà wa di ohun ti o rẹsẹ walẹ̀ mọ.
  
Ìgbà o ya ijọba Sàró ni ko saaye fájèjì mọ.
 Konikaluku gboko ibomii lọ.
Kájèjì o pasẹ̀ dà onílẹ̀ fẹ lolẹ.
Ilẹ mọ ki Bangbade to fura.
Ọja to ku ò le sanwó eebo.
Eebo o si ni gba pẹ̀lẹ́
Ọmọ akátá ko ni gba dakun-baba-ọkọ-mi
Ọrọ ba sori àgbà kodò.
Banbgbade du bi kówó ò mọ tan.
Nibi o ti n sare lo ti pade awon alalupaida.
Won ni o mẹgbẹrun wa ko wa fi gba ẹgbẹta.
Gbade o ri ẹgbẹta gba to fi danu l’Ọta.
Okate ti boru ko too fura.
Sago ni Bangbade tun pada sẹri wo.
Nibi won gbe n fun won ni number ki won to dasọ ẹgbẹ jọda loke Agodi.
Ọrọ ree mo wakọ èdè gunlẹ

Olayemi ọmọ a-ji-fàrán-sètẹ́
Ẹran mẹta lemi o ni ba won pa laye n bi.
Emi o ni pasan
Emi o ni pofo
Emi o si niba won padanu nigbẹyin ọrọ.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment