Smiley face

E Wo Ohun Ti Abiyamo Se Nitori Omo Re

 Enikan lo fi foto kinni to wa loke yii sowo si mi, lai salaye ibi ti isele naa ti waye ni pato. Mo pada sori ero ayelukara lati se ofintoto isele naa. Leyin naa ni mo ri foto keji ati iketa, ati ibi ti isele naa ti gbe waye. Ilu New York Ni isele naa ti sele lodun 2010.



Mo ti koko fe gboju kuro nitori isele atijo ni, sugbon isele inu re mu mi lokan mo si pinnu lati te safefe fun yin.

Ko si ohun ti abiyamo aye ko le se lati gba emi omo re la. Ina n jo ni apa ibi kan ninu ile eleyii ti ko fi anfaani sile lati jade sita sugbon eefin ina naa ti gba gbogbo inu ile kanri.

Abiyamo to wa ninu aworan yii gbiyanju lati yo omo re jade lati oju ferese ki eefin ina ti n jo naa ma ba se isemba fun omo re nigba ti oun fun ra re n fa eefin naa si mu.

Ori ile, ajekerin ni won wa, e yi to je wi pe siso omo naa sile le se ijamba fun omo naa gidigidi. Awon ara adugbo duro won woran, kosi seni to le se ohunkohun ju ki won pe awon osise panapana lo.


Bi abiyamo se fa omo re lowo dani ni yii titi ti iranlowo fi de. Bi o tile je wi pe ko rorun, sugbon abiyamo setan lati se ohunkohun lati gba emi omo re la, ko ti le bikita ki emi ara tie gan-an bo sii.

Yoruba ni ti ina ba n jo ni ti n jo omo eni, tara eni laa ko gbon danu. Sugbon nipa ife iya si omo, abiyamo yo omo re ninu isoro saaju ki oun fun ra re to rona jade.

Adura mi ni wi pe, wahala obi ko ni ja sasan lori omo. Awon omo wa yoo diru-digba loju emi wa. Nigba ti isu omo ba jina, akokoro ko ni mu wa lenu. Amin

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment