Ile ise olopa ile Nigeria ti pari iwadii re eleyii to mu dajusaka wi pe ofin ilana ati agbekale to nii se pelu yinyan awon oloye agba nile igbimo asofin agba ni awon kan ti towo bo loju ni ona alumonkoroyi ki erogba won le wa si imuse.
Gege bi a se gbo, ofin ilana ati yiyan awon oloye agba ti won se lodun 2011 eleyii ti awon omo igbimo asofin eleekeje tele ti yato si eyi ti awon omo ile igbimo eleekejo to wa loju opon bayii n lo.
Gege bi abajade iwadii ile ise olopa ile Nigeria eleyii ti oga olopa yan-an ile Nigeria, ogbeni Solomon Arase se so, won ni ofin ti won se lodun 2011 ko menu ba idibo awon oloye agba ile igbimo asofin nipa lilo ero igbalode tabi idibo mosinu-mosikun.
Sugbon iyalenu lo je nigba ti won tun si iwe ofin ilana ati agbekale naa wo ti won si ba awon nnkan won yii nibe.
Eyi fidi re mule wi pe eto idibo to gbe Bukola Saraki, to je aare ile igbimo asofin ati igbakeji re, Ike Ekweremadu wole je ona eru nipa yiyi iwe ofin ati ilana agbekale ile igbimo asofin agba.
Abajade iwadii yii ni ile ise awon olopa si ti fi ranse si Aare Muhammadu Buhari, eni to jeje niwaju gbogbo aye nikete ti won yan si ipo aare wi pe :" Mo wa fun gbogbo eniyan bakan naa ni mi o si fun enikeni."
Gege bi onimo ofin kan se so nipa isele naa, o ni yiyi iwe ofin ilana ati agbekale ile igbimo asofin je oran nla eleyii ti ijiya re je ewon odun meta gbako.
Awon wo ni won yii iwe ofin yii?
Igba wo ni won yi pada?
Awon obayeje wo lo si wa nidi oro naa?
Subscribe to:
Post Comments
(
Atom
)
0 comments:
Post a Comment