Gege bi iwadii, Baba Aare Ilu Kenya lowolowo bayii, oloogbe Jomo Kenyatta, eni ti oun naa ti fi igba kan je Aare ilu naa laaarin odun 1964 si 1978 ti fi igba kan da baba to bi Barack Obama duro lenu ise ri.
Baba to bi Barack Obama n sise labe ijoba igba naa gege bi onimo eto oro-aje (Economist) ni eka eto isuna owo nigba naa ki won to gba ije lenu re.
Gege bi a se gbo, bi Jomo Kenyatta se da baba to bi Barack Obama duro lenu ise lodun 1969 nigba naa se akoba, o si tun mu ifaseyin deba idile Obama. Ironu ati Ibanuje okan nipa bi won se da baba Obama duro lenu ise so di olotin amupara.
Baba Obama pada ni ijamba oko eleyii to si mu padanu ese re mejeeji.
Barack Obama pada wo ilu Kenya gege bi Aare to lagbara ju lagbaye pelu okiki nla, ti omo eni to da baba re duro lenu ise, Aare Uhuru Kenyatta si wa pade re ni papako ofurufu lati ki kaabo pelu iteriba ati aponle alailodiwon.
Pelu isele yii, a le gba wi pe ibanuje odun 1969 ti pada di ogo ati iyi nla fun gbogbo idile Obama ni ilu Kenyan.
Subscribe to:
Post Comments
(
Atom
)
0 comments:
Post a Comment