Adewale Dada Thegood |
Pẹlu
awọn alaye yii, sibẹsibẹ, mo fẹ ki ẹ mu ọkan yin le koko bi ọta. Ki ẹ si fi aye
silẹ fun eefin ireti ati igbagbọ yin lati ru soke lalaala. Nitori wi pe, ninu
ireti ati igbagbọ ni isẹgun ati ayọ wa wà.
Awon
àkókò ti Naijiria wa bayii jẹ àkókò ti gbogbo ọgbọn ti a gbọn ti jawa kulẹ.
Gbogbo awọn eniyan ti a gbara le lo si dabi ẹni wi pe won ti gbagbe wa sibi taa
wa laibikita.
Aimoye
ibeere lo pakasọ fun awon olórí wa ti wọn ko si ri idahun gidi sọ jade. Gbogbo
ìgbà ni awon ti a yan sipo si n foju pamọ fun wa nikete ti won ba pade wa
laaarin ọja.
Eto
ọrọ-ajé ilu wa si ti dabi àbíkú eleyii to wa lẹsẹ kan aye, ẹ se okan ọrun
bayii. Ti ẹnikẹni ko si le sọ ohun ti yoo sẹlẹ si i nigbakuugba sigba taa wa
yii.
Ounjẹ ti dọwọn gogo bi oju, epo rọ̀bì to ye ko jẹ ohun amusagbara wa lo tun
sokunfa inira wa. Ọpọ awon ọmọ orileede yii lo ti ro igbe aye won pin, awon kan
tilẹ n gbero
iku gẹgẹ bi ọna abayọ kan soso.
Pẹlu
awọn nnkan to n sẹlẹ yii, njẹ ireti tilẹ wa fun wa lorileede Naijiria? Njẹ a
tilẹ le sẹgun, ka si tun bori laasigbo ta a wa yii?
Nibi
ti mo de yii, maa rọ̀yín kẹ ẹ jẹ ka jọ rin irin-ajo pada sọdun 1519. Ni ọdun
1519 ni orileede Spain mura ogun lati kolu Aztec Empire (Aztec Empire lo pada
di Mexico lonii).
Hernan Cortes ni akọgun to lewaju fun awon ọmọ ogun ilẹ Spain ti wọn fẹ
lọ kogun ja Aztec Empire. Nigba ti ọkọ̀ oju omi won de ebute, niluu awon ọ̀tá,
Cortes pasẹ fun awọn ọmọ ogun rẹ lati danasun awọn ọkọ̀ ojú omi ti won gbe wa
pata.
Pedro de Alvarado to je igbakeji Cortes ko le ta
a lẹnu bẹẹ idi ti Cortes fi pa iru asẹ yii ko ye ẹnikẹni. Won sọ ina si
awon ọkọ̀ oju omi won, bi efin se n lọ soke ti n jo laulau ni Cortes gun ori
apata kekere kan lọ bẹẹ lo si gbe òhun rẹ soke wi pe:
“E jẹ ko ye gbogbo yin wi pe ko si ọ̀nà àbùjà lọrun ọpẹ. Ki ẹnikẹni ma si se pasamọ mọ̀jà-mọ̀sá laa mọ akikanju loju ogun. Anfaani meji pere lo si silẹ fun wa: ninu ki gbogbo wa parun tabi ka sẹgun; ko si aye lati sa sẹyin tabi pada sile laisẹgun. Idi eleyii lẹ fi ri awọn ọkọ̀ oju omi wa ti won deeru lọ diẹdiẹ loju yin.”
Lẹyinọrẹyin, ilu Spain sẹgun, won kẹ́rú-kẹ́rù
ni Aztec Empire. Awon naa ni won si pada jẹ gàba lewọn lori gẹgẹ bi amununisin.
Ẹ jẹ ka tun
wọ inu apilẹkọ John P.Schmal, eleyii to kọ lọdun 2004 to pe akọle rẹ ni THE RISE OF THE AZTEC EMPIRE.
Schmal gbe
apilekọ rẹ lori ọlá, iyì, agbára, ògo ati ẹwà Aztec Empire. Ninu alaye rẹ lo si fi kun un wi pe, ọkan lara awon ilu
alagbara ju lọ akoko naa tun ni wọn se.
Schmal ko sai pe akiyesi wa si ogunlọgọ awon
iwe Ọjọgbọn Micheal E. Smith to je olukọ ni Ifafiti ti ilu New York, ẹni to ti
kọ aimọye iwe lori Aztec Empire, lati gbe awon alaye rẹ lẹsẹ gẹgẹ bi okodoro ọrọ.
Ọ̀gangan ibi ti mo n lọ gan-an ni mo de yii,
ohun si lọ̀rọ̀ to jade lẹnu Cortes lọ́jọ́ ti wọn yẹsi pẹlu ami-ẹyẹ nipa aseyọri
rẹ pẹlu bo se lewaju ikọ̀ ogun Spain.
“Awọn ọmọ ogun ta a ko lọ soju ogun ko to nnkankan ti a ba ni ka fi we ti Aztec Empire. Bẹẹ ni awon ohun ija ogun ta a ko de Spain kere pupọ. Sugbon ohun kan lani lọpọlọpọ, ohun naa si ni agbara imunilọkanle lati sẹgun labẹ botiwukori. Eleyii ni igbagbọ wa rọmọ, nitori ona kankan soso ni yii lati wa laaye.”
Lonii ilẹ to
mọ, Hernan
Cortes ko si mọ, akikanju jagunjagun ti n fi ata gigun fin taba simu,
akọgun-oosa ti won fori balẹ fun loju ija, sugbon igbagbọ, ireti ati imulọkanle
rẹ si n sẹgun dọla fun awon to ba setan lati tọ ipasẹ rẹ.
Naijiria si
ma dun, ẹ jẹ ka fi igbagbọ ati ireti wa si i. Ka si maa káàárẹ̀ lati ri daju wi
pe a se ohun gbogbo lati mu nnkan pada bọ sipo. Ẹ jẹ ka pa ebi mọnu lonii,
ireti wa fun ọjọ ọla wa ti a ba duro lori òdodo.
Awon ipinlẹ ti won tori iresi abọ meji dibo
ni won ti pada kabamọ igbesẹ wọn. O ye ka ti
gbon, ka si ko lati maa fun awon ọjẹlu laaye ninu isejọba wa.
Eleyii si gbọdọ bẹrẹ lati adugbo wa, to fi de
ijọba ibilẹ, ipinlẹ ati awon asoju wa loke tente. Ẹnikẹni to ba fẹ gbe apoti
idibo, ẹ je ka beere itan rẹ. Ko di igba to ba to gbe apoti ko to se ojuse rẹ
fun idagbasoke ilu.
Ẹ jẹ ka se iwadii iru imọ ti wọn ni ati awọn
nnkan ti won ni lérò lati se? Kini eto won ati ipinnu won fun awon eniyan?
Olúborí ibẹ ni wi pe, a n fẹ awọn eniyan
ọ̀tun lagbo isejọba wa (mi o sọ wi pe awon eniyan tuntun). Ojuse awa ara ilu si
ni lati ri aridaju eleyii fun ọjọ iwaju wa.
Eyi lo fi jẹ
ki inu mi dun nigba ti mo gbọ nipa akitiyan awọn
eniyan ti wọn gbe ni agbegbe Sango Ota to wa nipinle Ogun lati se atileyin fun
Adewale Dada Thegood to n gbiyanju lati dije fun ipo alaga Ijoba Ibile
Ado-Odo/Ọta.
Adewale Dada Thegood |
Adewale Dada ti se aimoye ohun meremere
lati yi igbe aye aimoye awon eniyan awujo rẹ pada si rere.
Awon nnkan wonyii ko si pamọ rara. Pupo
ninu awon ilakaka ati iponlogo re fun idajọ ododo, iduroṣinṣin ẹtọ ọmọniyan ati
ọrọ isiti wa lara ohun to mu ijọba awaarawa rẹsẹ walẹ lonii.
Eleyii ti n ma se afiahan rẹ laipe ati
awon eniyan ọtun mii ti won tun dide pẹlu igbagbọ ati ireti lati mu igba dẹrun
fun tẹrutọmọ.
Ki
n to danuduro, ki owo wa le te ọjọ iwaju rere, a ni lati ni ìròrí tuntun,
igbagbọ ati imulọkanle lai boju wẹyin.
Awon
eniyan ọtun ti won jẹ olododo si wa layika wa, ẹ jẹ ka sawari won, ẹ jẹ ka se
atilẹyin fun won lai wo tẹsin, ẹgbẹ oselu ati ẹ̀yà won. Ohun to kere ju ti a le
se ni yii lati mu orileede yii goke àgbà.
Ibi
ti ma ti duro ni yii. Olayemi Olatilewa
ni oruko mi, ilu Naija ni mo n gbe, ilu awọn onilaakaye ẹda ati
oniwa tutu bi àdàbà. Ki Oluwa ki o bukun un lọpọlọpọ. Amin.
E je ka fi ipade si ori YORUBA DUN nibi ti awon eniyan ti n se alaye nipa taani ojulowo omoluabi
0 comments:
Post a Comment