![]() |
Ogun Omode Kii Sere Fun Ogun Odun |
O je ohun to ba ni
lokan je, eyi si wa lara iriri to seese ki n maa gbagbe lailai. Akiyesi igbe aye fi ye mi wi pe aimoye imo
iyebiye ni eda le ba pade lai se wi pe enikan peni joko salaye ohun to ruju bi
igba omo ile iwe joko kawe ni kilaasi.
Mo ranti Musa lonii,
okan lara awon ore mi ni Musa je nigba ti mo wa ni ile eko alakobere. Ile Eko Alakobere
Metodiisi ti o wa ni Ekotedo ni mo lo ni ilu Ibadan. Akoko eko mi yii si je
okan lara igbe aye mi to dun pupo. Orisii igbe aye ti o je wi pe ere sise loba
awure. Igbe aye ti o je wi pe ko si ohun meji ju ayo lo, a ko le ohunkohun
bakan naa ni nnkankan o si le wa.
E ru orisii opolo
Musa a maa ba mi leru nitori mi o fi ibi Kankan sunmo nibi ise opolo sibe joojumo
lemi n wa si ile iwe. A si maa wu mi ki n dabi Musa omo Ibrahim.
Musa nikan ko lowu
mi ki n jo. Okan lara awon ore mi kan naa tun wa to tun fara pe, Hamzat. Kii se
opolo pipe lo mu Hamzat wu mi. Sugbon mo feran Hanzat nipa ewa ara to ni. Ti
won ba ni okunrin rewa, ati ojo ti won ti bimi saye mi o ti ri iru ewa Hamzat
ri. Hamzat mo fefe, pupa re si la kedere
bi oye la kari aye.
Irun ori re a
maa gbon leuleu bi o ba n rin lo bi irun eebo. (Omo Niger Republic loke oya
loun ni iya re, won si ni iya re ni o fi irun naa jo) Hamzat tun ni orisii
ohun(voice) kan eyi ti o je wi pe ti o ba n binu soro eniyan o le mo wi pe oun binu ni. Ki ohun (voice) eni o tutu
ko si maa si agbara ibinu to le yi pada kuro ni ipo re.
Imo je ohun to se
koko si igbasi aye eda. Ebun nini si tun je ore-ofe lati odo Olorun lati se
aponle eda fun igbega. Sugbon olubori ibe ni iwa. Awon kan pe ni isesi tabi
iha. Ohun kan naa ni gbogbo re ja si.
Isesi eni lo maa n fi iwa owo eni han. Iwa owo
eni si ni opakutele si iha eni si ohunkohun
ti a ba gbe dani tabi doju ko laye.
Bi Musa se ni
opolopo opolo to fun iwe kika, iha to ko si eko re pada so imo re di akurete. Ohun
ti oluko ko wa laaarin wakati kan seyin, agaga ti a ba jade lo sere ki a to tun
pada si kilaasi, maa ti gbagbe opolopo nnkan ti won ko wa. Bi Musa ba sa ni ile
iwe fun ose meji, eyo woro kan eko to ti ko seyin ko ni bo sonu latari re.
Igba meji otooto
ni mo tun yara ikawe meji otooto ka nigba naa. Musa ko tun yara kan ka leemeji
ri.
Emi pada wo ile iwe
girama, Musa o le lo. Won tun gbami wole si
Ifafiti, Musa gbiyanju sugbon aso o ba Omoye mo.
O ku die ka jade ile
iwe alakobere ni Hamzat bere si ni tele awon orekore ti won n jijo lo maa mu
imukumu. Igba ti mo wo ile iwe girama, Hamzat naa o le wole pelu wa nitori wi
pe igbo ti yi lori. O si ti bere si ni wi kantakantan kiri. Okan mi baje. Awon
obi re mu lo seyin odi lati lo toju re. Igba ti Hamzat yoo fi pada wa sile. Awo
re ti si, oju re ti hun jo bi oju agbalagba , omo pupa ti jona bi eyin ape
akara, irun ori re ti reje tan bi igba ogun jalu, bakan naa ni gangangan ko kuro lara re tan
patapata.
Igba miiran yoo tutu bi omi inu amu. Bee ba n baa soro ko ni
wi ohunkohun. Igba mi si ree, erin odi ni o maa rin lenu. Hamzat ko riran ri
ara re debi wi pe yoo se itoju ara re gege bi o ti ye.
Musa ati Hamzat je
ore mi igba kekere ti a jo lo ile iwe kan naa ti a si tun jo gbe ni adugbo kan
naa. Bi o tile je wi pe ogun omode o le sere fun ogun odun. Sibesibe, sebi ojo
taa ba ri ara eni o ye a dun nu ni? Hamzat o da mi mo moo lojo ti mo duro ki i,
ti Musa ba ri mi a foju pamo.
Mo padanu won ki i
se nipa iku bi ko se nipa igbe aye won to loju nipa iwa ati isesi won.
Kosi iru ogbon ti
eda le wu ko ni laye, kosi iru ebun ti Edua oke le fi jinki eniyan, ko de si
iru imo to le wa latari eni, bi eniyan ba padanu iwa tabi ti isesi eni ba kudie
kaato tabi ti iha eni ba mehe, omoluabi iru eni bee ko le duro.
Musa ati Hamzat je
awon ore mi ti mi o le gbagbe lailai. Musa padanu opolo pipe, Hamzat si so aye
re nu lati mojesin.
Olayemi Oniroyin,
gbogbo igba lokan mi maa n baje ti mo ba ranti awon ore mi meji yii.
Awon ore mi meji ti
mi o le gbagbe lailai.
lwa se pataki ose koko, ju gbogbo re lo, ki a ranti omo eni ti awa nse.
ReplyDelete