![]() |
Bashorun Gaa Egbe PDP: Bamanga Tukur |
Joojumo ni n gbona felifeli bi pofupoofu iya Dele to wa l'Ojota, oro oselu ati darudapo ti n waye ninu egbe PDP naa ni.
Nibayii, awon alaga egbe PDP ni awon Ipinle gbogbo to fi mo ti olu ilu Naijeria ni won ti wo aso odi fun alaga egbe PDP lapapo, Alhaji Bamanga Tukur wi pe ko maa lo si ile.
Ana ode yii ni gbogbo won towo bo iwe A-ko-fe-o-mo-Bamanga-Turku-maa-lo.
Se Bamanga Tukur yoo lo looto abi oro awada lasan ni?
Kini yoo sele si eto idibo Aare Goodluck lati pada di Aare lodun 2015 ti irawo Tukur ba ja loju orun?
Ti yoo ba fi di iwoyii ola, gbogbo re yoo ti lojutu.
0 comments:
Post a Comment