Smiley face

Kini Idi Pataki Ti Aare Goodluck Jonathan Fi N Ko Leta Iku Ranse Si Buhari, Bisi Akande Ati Tinubu?

Bi o tile je wi pe oludamoran fun eto iroyin fun ijoba Goodluck tako awuyewuye to gba gbogbo inu iroyin kankan, sibesibe oro agba ki i gbele lasan. Awon agba loni isele ki i se ko ma seni loju firi.

Awon eniyan sankosanko ninu egbe alatako ti fesun kan Aare ile Naijeria, Goodluck Jonathan wi pe o n lepa emi awon lati pa.

Awuyewuye yii lo waye leyin asiri akosile Aare kan to tu jade eleyii ti o ti se akosile awon wonyii gege bi ota ijoba pelu apejuwe won to pe ni 'Awon-a-gbe-inu-okunkun-tafa-si-inu-imole'.

Awon ti oruko won jade ninu iwe akosile naa ni Ajagunfehinti Muhammadu Buhari, Gomina Rotimi
Amaechi ti Ipinle Rivers ati alaga egbe APC, Oloye Bisi Akande.

Ninu iwe yii kan naa ni oruko minisita ilu Abuja nigba kan ri ti jade, Mallam Nasir el-
Rufai.

Awon wonyii si ti fesi wi pe owo Olorun ni emi awon wa, ati wi pe eni ti Olorun ko pa ko si iyanlaya eni le fi leta iku de iru eni bee.

Won ni awon tile mo tele wi pe aja ki i se ore ekun, ekun kii si se ore aja. Bi ekun ba fe lo agbara to ni lati fi je aja niya, ki ekun naa se iranti Oba Yaradu to lagbara ju aye lo.

Sugbon sa, Ogbeni Reuben Abati to je oludamoran nipa iroyin ati oro to n lo fun ijoba apapo so wi pe iro lasan ni aheso naa.

Gege bi oro re, oni ofutufeete aasa ti o ni kaun ni oro naa.

O si pe awon egbe alatako nija wi pe ti won ba ni eri nipa akosile Aare eleyii to se apejuwe won gege bi agbe inu okunkun tafa sinu imo eleyii ti aare si setan lati lo ete eni yara l'Ogun n gbe nipa siseku pa won ki won jade wa wi fun gbogbo araye.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment