Smiley face

Olorun Nikan Lo Le Gba Emi Adams Oshiomole La



Iroyin ti kan wa wi pe ipo ilera Gomina Adams Oshiomole ti Ipinle Edo tun bo n buru si ni Ilu Oba (United Kingdom) ti won gbe lo fun itoju.

Gomina Oshiomole ni ijamba oko ni nnkan bi ojo melo kan seyin eleyii to mu won gbe digbadigba so sinu baalu ofurufu lati lo se ise abe to ni i se pelu opolo ni ilu okeere.


Nibayii, iroyin to kan wa ni wi pe kaka ko san lara omo iya aje, gbogbo omo to n bi obirin ni. Ipo ilera Gomina Adams to ye ko maa pada bosipo lowo awon agbaoje dokita akosemose alaso funfun ti won dooyi yika tun bo n ba ni lokan je si ni.

Oba Oluwa nikan lo le gba okurin to ti fi igba kan je olori egbe osise ile Naijeria sile lowo inira eleyii ti enikeni ko le so bi igbeyin yoo se ri ti iru inira naa ba tesiwaju.

Adura wa ni wi pe oba to ji oku ojo meta dide yoo fi owo kan Gomina Adams Oshiomole. Amin

Olayemi Oniroyin ni emi nje, Oba Oluwa si ni igbekele mi.
E ku alaja odun


Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment