Smiley face

Boko Haram Ti Ko Leta Iku Si Ilu Cameroon


Awon Boko Haram ti ko leta si ile Cameroon to je alamulegbe ile Naijeria pelu bi won se n yojuran si ohun ti o kan won rara. Ile Cameroon lagbo wi pe o n se atileyin fun awon omo ologun Naijeri ti won gbogun ti Boko Haram lati dekun awon iwa ika owo won ni awon ilu to wa ni Oke Oya Naijeria.

Gege bi a se gbo, nikete ti awon omo Boko Haram ba pari ise ibi owo won tan, ilu Cameroon, Niger ati Chad ni won lo n fori pamo si eleyii ti ko si leto labe ofin agbaye fun soja ilu kan lati jawo ilu mii.

Nibayii, awon omo ogun ilu Camerron n fina mo awon omo Boko Haram ti won sa wo ilu won tabi agbegbe ilu naa lati sa pada si ibi ti won ti n bo ki owo awon omo ologun Naijeria le te won.

Ilu Cameroon dide iranlowo yii latari abewo kan ti Aare Goodluck se si Aare ilu naa nibi to ti lo beere fun atileyin ati ajosepo igbogun ti Boko Haram.


Sugbon bayii awon omo Boko Haram ti fi ede Hausa ko leta si Aare ilu Cameroon, Paul Biya. Bi won se ko leta naa ni yii:

Sii Aare Paul Biya,
Awon Yoruba ni won wi pe a wi fun ni ko to dani, agba ijakadi ni. Ohun ti won ba si fi Elemosho so nii so. Ti o ko ba fe ki a je ilu re run bi igba ti ikan n je ile, ma dasi oro awa ati ile Naijeria mo. Ni ojo ti awon omo ogun re ba tun se apa bi itan, ti won saya bi eyin ojo naa lo gba wi pe eran to ba yi ni won n pe ni namo.

Awa Ni Ti E Loju Ogun
Boko Haram
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment