Smiley face

Aare Jonathan Ti Je Gbese: Awon Omo Gambari Ti Fa Ibinu Yo Ni Kaduna

Awon eniyan ti won n gbe ni Guusu Kaduna ti bere si ni ko ara won jo lati ri daju wi pe Aare Jonatha fidiremi ninu eto idibo odun to n bo.

Gege bi e se mo, lojo Abameta to koja ni awon abule bi Ugwar Sankwai, Ungwar Gata ati Chenshyi ti won wa ni Ijoba Ibile Kaura ni awon agbebon kan kolu ti won si fi eje awon eniyan bi ogorun we lai se Ogun Onire pelu opolopo dukia ti won jo nina wuruwuru.

Lati igba ti isele yii ti sele Aare ko tile sebi eni wi pe oun gbo si isele naa rara, bakan naa ni igbakeji re ko si sebi eni wi pe oun naa mo si i rara.

Oro yii bi awon eniyan Guusu Kaduna ninu won si ti bere si ni so wi pe eto idibo odun 2015, ofo ojo keji oja ni yoo je fun Aare Goodluck Jonathan.

Olori egbe awon eniyan yii, Omowe John Danfulani se alaye edun ati ero okan won fun awon oniroyin nigba ti n se alaye isele to waye naa.

E gbo ohun to so:

"President Jonathan does not care and therefore does not deserve the votes of the bleeding Southern Kaduna people in 2015."

"We cannot allow politicians take
our existence for granted. We will mobilise our people to vote against Governor Ramalan Yero, Namadi Sambo and Goodluck Jonathan in 2015 as a protest against their insensitivity to the killings in Southern Kaduna and their failure to honour our dead who have been slaughtered
under their stewardship."
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment