Smiley face

Omo Kekere IBB Seku Pa Ore Lojo Tore Dale Ore Niwaju Agbara Ati Ipo


Awon Yoruba ni ori taa fi sewe kii kuro lorun eni taa ba dagbalagba. Ibrahim Badamosi Babangida ni yii laye alalumole.

Ore re, Mamman Jiya Vatsa lo duro ti i legbe nigba won jo je omode ninu ise ologun.

Awon mejeeji pada di oga nla ninu ise ologun ni, sebi omo kekere naa ni i dagbalagba.

Sugbon lojo karun-un osu keta odun 1986 Ibrahim Babangida se idajo iku fun ore re latari igbiyanju re lati dite gba ijoba lowo IBB.

Ojo ketadinlogun osu kejo odun 1941 ni won bi Babangida (17/8/1941); ojo keta osu kejila odun 1940 ni won bi Mamman Vatsa (3/12/1940) to je imule ati ore timotimo IBB lati kekere.

Sugbon lojo kan, ore dale ore. Ore si ko lati darijin ore. Ore dajo iku fore. A ni lojo kan, ore ja irawo ore loju orun lojo ti Agbara, Ipo, Owo ati Okiki se pataki.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment