Smiley face

Awada Ojo Isinmi

E wa, e je ka rerin-in sannde!

Obinrin alaboyun kan n robi fun opolopo wakati, sugbon ko jo pe
omo naa fe wa rara, pelu bawon noosi se n pariwo fun un pe ko
"gbin!" daadaa to.


Leyin bi iseju marun-un sii, omo tuntun naa yoju. O si beere
awon ibeere kan lowo noosi:


Omo: E dakun, se Nigeria ko yi?

Noosi: Bee ni. Nigeria ni.

Omo: Boko Haram nko. Se won si wa sibe, ti won n paayan?

Noosi: Bee ni.

Omo: Awon oluko ASUP nko?

Noosi: Won si wa lenu iyanselodi won.

Omo: Ogun bilionu owo ile okeere, $20billlion ti won lo sonu nko?

Noosi: Won o tii rii.

Omo: Chai! Awon akekoo-binrin Chibok nko? Se won ti ri won
gba?

Noosi: Rara.

Omo: Ajo onina NEPA nko... se won ti n tan'na deedee?

Noosi: Nibo? Se o o rii pe ina ori foonu mi la fe fi gbebi re ni?

Omo: Se Jonna si ni aare ni?

Noosi: Bee ni.

Omo: Iyawo re nko?

Noosi: O si n sunkun pe, Daris Gooodu oo!!!

Omo: Kai! Se egbe oselu APC ati PDP si n naka aleebu sira won,
ti won n ti oran mora won lori awon isele to ba se?

Noosi: Bee ni.

Omo: Se won si n se ipade apero lowo l'Abuja?

Noosi: Bee ni.

Omo: Aaaaaaaaaaah!!! Esu jebi... Emi ko, mi o jade mo!!

E ma daa rerin-in yi o.

A ku isinmi sannde. A si ku odun aawe yi.


Lati Owo: Yanju Adegboyega.

posted from Bloggeroid

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment