Smiley face

Boko Haram Pa Ogota Eniyan Ni Adamawa Ni Ojo Kinni Osu Kefa Odun 2014


Awon omo ogun alakatakiti esin ti a mo si Boko Haram tun ti seku pa awon eniyan ti won ko din ni ogota (60) ni ile asewo kan ti awon eniyan ti maa n gbadun ara won ni ilu Adamawa.  Ile asewo yii ti ko jina si ibujoko awon omo ologun Naijeria ni won ju ado oloro iku si ni nnkan bi ago mefa irole ojo Aiku to koja yii (1/6/14).  

Gege bi a se gbo, opolopo awon Soja ni won maa lo si ile asewo naa lati lo se faaji ara won, aimoye awon eniyan naa ni won  maa lo sibe lo mu otin tutu. Sugbon titi di akoko yii, a ko ti le so boya Soja wa ninu awon ti ado iku mu lo ni ile igbadun to pada di ile iku fun awon eniyan bi ogota. 
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment