Smiley face

Dora Akunyili Pada Ku Fota Yo.

Ojo ti Gaa Bashorun Oyo Ajaka ku.
Alaafin Abiodun Adegoolu lo koko jo.
Gbogbo Oyo n dunnu, won ni eniibi lo.


Ojo ti won pa Muritala ni ilu kan gogo.
Aimoye awon eniyan ni i sukun sedaro omo Momodu.


Dora ti ku, awon ota n dun nu.
Won ni sebi awon ti wi fun un wi pe bi aja re lo ogun odun laye,
Eran Ogun ni i se.
Won fi iku yo akoni nitori ise opolo.
Won jo, won yo lojo akikanju subu.
Won fi otin oyinbo sere lojo ti won gbo iku Dora Obirin rere.

Ilekun ile ise ayederu ogun oyinbo ti Dora tipa lojosi sebi ise oba lo je.
Kilowade ti awon ika eniyan n fo fayo?

Dora Akunyili ti ku o.
Abatabutu omi okun ti gbe raurau.
Eni to pe wa 'Leni Rere, Ilu Olokiki Nla' ti lo.
Dora Akunyili pada ku fota yo.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment