Smiley face

Won Ti Ri Ajaale Tuntun Ni Ilu Czech Republic

Ile ijosin kan to wa ni ilu Czech Republic ni won ti ri ajaale kan eleyii ti won se akiyesi re leyin opolopo odun ti ajaale naa ti wa nibe. Gege akiyesi won, won ni awon eniyan ile ijosin naa ti won ti papoda laimoye odun seyin ni won sin sinu ajaale naa nitori won ri awon ohun elo ijosin won bi rosary lara awon oku ti won sin sibe. 


Enikeni ko le so iye odun ti awon oku naa ti wa nibe, sugbon ohun to daju ni wi pe awon oku naa kii se ti iran yii rara.

Akojopo awon oluwadii  fi ye wa wi pe idi pataki ti ko je ki oku awon eniyan yii jera patapata nii se pelu orisii iyepe ti won gbe oku won le, ati awon ategun alaafia emi mimo ti n fe ninu ajaale naa. 


Ijo Olorun yii ti se atunse ajaale naa daada pelu itoju awon oku to wa nibe. Nibayii, won pe gbogbo eniyan lati wa wo ise iyanu awon oku ti won dengepo pelu swagger to fakiki. 

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment